Ọga ile ẹkọ girama to ba gba owo ti ko to lọwọ àwọn akẹkọọ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ - Ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 26, 2022

Ọga ile ẹkọ girama to ba gba owo ti ko to lọwọ àwọn akẹkọọ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ - Ijọba KwaraIjọba ipinlẹ Kwara ti ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn ọga agba pata l'awọn ile ẹkọ girama lati dẹkun gbigba awọn owo ti ko tọ lọwọ awọn akẹkọọ, ati pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.

Akọwe agba lẹka eto ẹkọ ati idagbasoke ọmọniyan, Arabinrin Mary Kẹmi Adeọṣun lo sọ eyi di mimọ lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii, lakoko to n ba gbogbo awọn ọga agba ile ẹkọ girama ṣe ipade nile ẹkọ girama ti Saint Anthony to wa niluu Ilọrin.

O ni gbogbo awọn ọga agba pata l'awọn ile ẹkọ girama to wa kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindilogun ni ipinlẹ naa ni ọrọ yii n bawi, lai yọ ẹnikẹni silẹ.

Nibẹ ni Adeọṣun ti jẹ ko di mimọ pe owo ẹgbẹ ipade obi ati olukọ, iyẹn PTA nikan ni ijọba fọwọ si, ṣugbọn ṣa, ọga agba to ba gba kọja owo naa yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

O wa ṣapejuwe awọn owo ti ijọba fi ontẹ lu fawọn akẹkọọ lati san gẹgẹ bii:

PTA:

JSS - 1,450  
SSS - 1,500  

AWỌN TO ṢẸṢẸ WỌLE/NEW INTAKE:
JSS - 3,930
SSS - 3,980

IWE KIKA/TEXTBOOKS:
JSS - 4,500
SSS - 5,600

IWE IBEERE ATI IDAHUN BECE/BECE QUESTION AND ANSWER: 1,800.

O wa rọ gbogbo awọn olori kaakiri ile ẹkọ lati fọwọsowọpọ pẹlu iṣakoso Gomina AbddulRahman AbdulRazaq tọkantọkan, nitori pe ọrọ awọn olukọ jẹ ẹ logun gidi, eyi to mu ko maa na owo sibẹ

Bakan naa lo tun rọ awọn ọga agba lati maa jẹ ki awọn akẹkọọ wa ninu ọgba ile ẹkọ nitori akẹkọọ ti ọwọ ba tẹ, to n ri gberegbere kaakiri igboro yoo jiya labẹ ofin.

Bẹẹ lo tun ran wọn leti pe ọga agba kankan ko gbọdọ gba akẹkọọ wọle si kilaasi SS1 lai jẹ pe wọn ri esi idanwo BECE, ati pe wọn ko gbọdọ gba akẹkọọ to pọ ju, o ni ki akẹkọọ to ba fẹẹ wọle wa ile ẹkọ miran to sunmọ lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI