Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun wọ gau, lọwọ EFCC ba tẹ ẹ ni papakọ ofurufu l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 1, 2022

Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun wọ gau, lọwọ EFCC ba tẹ ẹ ni papakọ ofurufu l'Ekoo


Iroyin to lu igboro bayii ni pe ọwọ ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti tẹ olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ lori ẹsun jibiti.
 
Papakọ ofurufu ti Muritala Muhammed to wa ni Ikẹja, niluu Eko la gbọ pe ọwọ palaba rẹ ti segi laarọ oni, Ọjọbọ, Toṣide, lakoko to fẹ maa rin irin ajo lọ s'oke okun.
 
Ẹsun jibiti owo la gbọ pe wọn fi kan Ọnarebu Oluọmọ to n ṣoju ẹkun Ifọ, ipinlẹ Ogun nile igbimọ aṣofin.
 
Ọpọ igba la gbọ pe ajọ EFCC ti ranṣẹ pe Ọnarebu Oluọmọ lati wa a sọ lori ẹsun ti wọn fi kan an, ṣugbọn to kọ lati lọ yọju si wọn, eyi lo fa a ti wọn fi n wa ọna lati dọdẹ rẹ mu.

Laipẹ, ẹkunrẹrẹ iroyin ọhun n bọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI