Ẹwọn ọdun mẹta n duro de ẹni to ba gun ọkada l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 1, 2022

Ẹwọn ọdun mẹta n duro de ẹni to ba gun ọkada l'Ekoo


Ijọba ipinlẹ Eko labẹ GOmina Babajide Sanwol-Olu ti sọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ wi pe o tapa si ofin gigun ọkada nigboro ilu Eko yoo fi ẹwọn ọdun mẹta gbako gbara pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
Kọmiṣanna f'ọrọ igbokegbodo ọkọ n'ipinlẹ naa, Ọmọwe Frederic Ọladẹinde lo fi ọrọ naa lede lakoko to n ṣe ipade papọ pẹlu awọn akọroyin lagbegbe Ikẹja, ipinlẹ naa.
 
O ni ipele keji ofin to de awọn ọlọkada maa bẹrẹ l'awọn ijọba mẹrin ọtọọtọ, ati ijọba ibilẹ idagbasoke mẹfa ọtọọtọ l'ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii.
 
Bẹ o ba gbagbe, ninu oṣu kẹjọ to ṣẹṣẹ pari yii ni ijọba ipinlẹ naa kede fifi ofin de ọlọkada l'awọn ijọba ibilẹ mẹrin ati ijọba ibilẹ idagbasoke mẹfa, iyẹn ni: Koṣọfẹ (ijọba ibilẹ idagbasoke Ikosi-Iṣẹri ati Agboyi-Ketu); Muṣhin (ijọba ibilẹ idagbasoke Odi-Olowo); Oṣhodi (ijọba ibilẹ idagbasoke Oshodi-Isọlọ ati Ejigbo), ati Ṣhomolu (ijọba ibilẹ idagbasoke Bariga).
 
"A n rawọ ẹbẹ si gbogbo araalu lati tẹle aṣẹ ati ofin, nitori pe ati ọlọkada, ati ẹni ti wọn fi ọkada gbe ni ofin naa n ba wi, wi pe wọn yoo fi ẹwọn ọdun mẹta gbara bi wọn ba fi le f'oju ba ile-ẹjọ.
 
"A maa tun gba ọkada wọn, ti a si maa run womuwomu nita gbangba, ni ibamu pẹlu ofin irinna Section 46, sub-section 1, 2 & 3 ti agbẹyẹwo, iyẹn Transport Sector Reform Law (TSRL), ọdun 2018."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI