Omiyale: ijọba Kwara b'awọn araalu Patigi kẹdun, wọn tun ṣeleri nla fun wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 28, 2022

Omiyale: ijọba Kwara b'awọn araalu Patigi kẹdun, wọn tun ṣeleri nla fun wọn


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbddulRahman AbdulRazaq ti ṣe abẹwo s'awọn ara agbegbe Gbaradogi ati Saachi, to wa nijọba ibilẹ Patigi lori ijamba omiyale to ṣọṣẹ nibẹ laipẹ yii.

Nigba to n ṣabẹwo s'awọn agbegbe ọhun lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii, igbakeji gomina, Kayọde Alabi sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ fun ijọba, ni kete ti wọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa.


AWIKONKO gbọ pe nibi abẹwo ọhun ni ijọba ti mọ pe gbogbo dukia wọn ni agbara ti gbe lọ tan.

Igbakeji gomina, Kayọde Alabi to ṣoju ọga rẹ ṣeleri wi pe ijọba yoo dide iranwọ fun gbogbo awọn to kagbako nibi ijamba naa. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI