O tan o! Wọn ju Ọhyakilomẹ at'awọn mẹrin ṣewọn n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, September 28, 2022

O tan o! Wọn ju Ọhyakilomẹ at'awọn mẹrin ṣewọn n'Ilọrin


Onidajọ Muhammed Sani ti ile ẹjọ giga apapọ, ẹka ti ilu Ilọrin ti ju awọn gendekunrin marun-un kan ṣewọn, lori ẹsun jibiti ori ikanni ayelujara ti a mọ si Yahoo-Yahoo.

Ẹsun ọtọọtọ la gbọ pe wọn fi kan awọn maraarun-un, eyi to nii ṣe pẹlu jibiti ati ilọnilọwọgba.

Jacob Emmanuel, Usman Teminu, Akerele Olugbenga, Abdulrazaq Ikoojo Ahmed ati Idemudia Ọhyakilomẹ Christian lorukọ wọn.

Ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii ni iroyin fi to wa leti pe wọn ju awọn eeyan yii ṣewọn ọtọọtọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI