Ọmọ mi ni Gẹnẹsis Global, Ọlọrun maa ba wa yanju ọrọ wa laipẹ - Wolii Esther Ajayi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 1, 2022

Ọmọ mi ni Gẹnẹsis Global, Ọlọrun maa ba wa yanju ọrọ wa laipẹ - Wolii Esther Ajayi


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi The Love of Christ Generation, Ajihinrere Iyaafin Esther Ajayi, ti sọ pe ko si ija kankan to n waye laaarin oun pẹlu olori ijọ Celestial Church of Christ (CCC), ẹka ti Genesis Global, Wolii Israel Ọladele Ogundipẹ, o ni ọmọ ni ọkunrin naa jẹ s'oun.
 
Laipẹ yii ni WOlii Gẹnẹsis sọrọ jade ninu fọnran kan to kaakiri ori ikanni ayelujara, nibi to ti n fi ẹsun kan Wolii Esther Ajayi, ẹni to mu gẹgẹ bi i mama, fun bo ṣe pa a ti, ti ko si dide s'oun lakoko t'oun wa ninu iṣoro.
 
O ni Wolii Ajayi ko yọju s'oun, bẹẹ si ni ko pe iyawo oun lati beere laafia oun lakoko t'oun wa lọgba ẹwọn nibi ti wọn ti ṣe idajọ lori ẹsun ti ko mọ nkankan nipa rẹ.
 
Wolii Ogundipẹ loun ti ṣiṣẹ sin Wolii Ajayi tọkantọkan bi i iya to bi oun, ṣugbọn to sọ ọ nita gbangba wi pe awọn ko jọ ni ajọsepọ kankan, ati pe o tun yọ fọto oun kuro ninu patako apejuwe awọn eto toun ti lọ, loun ti mọ pe iya naa ki i ṣe abiyamọ gidi.

Nigba to n f'esi Wolii Ajayi sọ pe ọmọ oun ninu ẹmi ni Ọladele Ogundipẹ jẹ, nitori ẹ l'oun ko ṣe ni ọrọ kankan lati sọ, ati pe Ọlọrun yoo ba wọn yanju ohunkohun to ba wa laaarin wọn.
 
Wolii Ajayi tẹsiwaju pe ayẹyẹ ọdun kẹẹdogun toun da ṣọọṣi silẹ niluu London n bọ lọna, ati ayẹyẹ idupẹ ọdun kan to da ṣọọṣi tilu Eko silẹ naa n bọ lọna, fun idi eyi, oun ko le jẹ ki ohunkohun di oun lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI