Paga! Oṣiṣẹ ijọba to n f'ayederu iwe igbanisiṣẹ lu jibiti ni Kwara wọ gau - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 29, 2022

Paga! Oṣiṣẹ ijọba to n f'ayederu iwe igbanisiṣẹ lu jibiti ni Kwara wọ gau


Beeyan ba ri Arabinrin Ọyawoye R. Ọlajumọkẹ Fafẹmi, yoo kọkọ ro pe eeyan Ọlọrun ní, ṣugbọn ti wọn ba fi arabalẹ daadaa, wọn yoo rii pe ko ni ẹmi Ọlọrun kankan ninu rara, o kan n fi orukọ Jesu boju lasan ni.

Eeyan ti ko din ni mẹtalelogun la gbọ pe obinrin naa fun ni iwe igbanisiṣẹ, to si ni ki wọn lọ bẹrẹ iṣẹ ni ẹka ileeṣẹ ijọba to pin onikaluku wọn si.

Awọn ọmọ ijọ rẹ la gbọ pe obinrin naa fun ni iwe igbanisiṣẹ, lẹyin to ti gba owo lọwọ wọn pẹlu ẹtanjẹ wi pe oun yoo ba wọn wa iṣẹ

Ẹka ileeṣẹ to n bojuto eto iṣuna la gbọ pe obinrin yii wa, to ti n ṣiṣẹ.

Ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii ni iroyin fi to wa leti pe ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC foju rẹ ba ile ẹjọ giga apapọ to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, iyẹn niwaju Onidajọ Mohammed Sani.

Ẹsun mẹrin ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu jibiti bii ẹtanjẹ nipa igbanisiṣẹ ati ẹtanjẹ nipa irin ajo lọ si ilẹ Hajj

Wọn ni ọpọlọpọ owo lo gba lọwọ awọn ọmọ ijọ rẹ ti Christ Apostolic Church to wa niluu Ọffa lati ba wọn wa iṣẹ ijọba ti ipinlẹ Kwara ati ti ijọba apapọ

Lẹyin ti wọn lo gba owo lọwọ wọn tan, lo ba tun lọ ṣe ayederu iwe igbanisiṣẹ fun gbogbo wọn. Ninu lẹta naa lo tun ti sọ ipele ti wọn yoo wa, ati iye owo oṣu ti wọn yoo maa gba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI