Aṣiri bi Ọjọgbọ Awodun ṣe fi orukọ ileeṣẹ ẹ gba iṣẹ lọwọ ijọba Kwara to ti n ṣiṣẹ lu sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 27, 2022

Aṣiri bi Ọjọgbọ Awodun ṣe fi orukọ ileeṣẹ ẹ gba iṣẹ lọwọ ijọba Kwara to ti n ṣiṣẹ lu sita


Kayeefi ni iroyin naa ṣi n jẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lori bi alakoso agba ana nileeṣẹ to n ri sọrọ ipawowọle fun ipinlẹ Kwara, Kwara State Internal Revenue Service (KW-IRS) ṣe fi orukọ ileeṣẹ ẹ gba iṣẹ lọwọ ileeṣẹ naa.
 
A gbọ pe obitibiti biliọnu naira ni akanṣe iṣẹ ti Ọjọgbọn Awodun gbe jade fun ileeṣẹ ijọba to ti jẹ olori, fun ileeṣẹ rẹ to da silẹ, CSDC Consulting Enterprise Solutions.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni oṣiṣẹ ijọba ko lẹtọọ lati fi orukọ ileeṣẹ rẹ gba iṣẹ lọwọ ijọba, ati pe iwa ọdaran pọmbele ni.
 
Wọn ni ninu ifọrọwerọ ti Ọjọgbọn Awodun ṣe pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin Thisday lọjọ kẹwaa, oṣu ti a wa yii lo ti sọ ọ wi pe oun ni alakoso agba to n mojuto ileeṣẹ CSDC Consulting Enterprise Solutions.
 
A gbọ pe ninu atẹjade ti ajọ MDAs gbe jade, ni wọn ti ṣalaye pe Awodun gba iṣẹ naa lati ra awọn irinṣẹ ẹrọ ayelujara ti a mọ si 'Software' ti wọn pe ni 'Amanda' lowo to ya ni lẹnu, ati pe awọn irinṣẹ naa ko ṣiṣẹ bi ijọba ṣe fẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI