Awọn olukọ Kwara tun bọ sinu igbadun ayeraye, ijọba fẹẹ kọ ile fun gbogbo wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 27, 2022

Awọn olukọ Kwara tun bọ sinu igbadun ayeraye, ijọba fẹẹ kọ ile fun gbogbo wọn


Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, inu idunnu ati ayọ nla ni awọn olukọ patapata jakejado ipinlẹ Kwara wa, lori bi ijọba ṣe ṣeleri kikọ ile-igbe fun gbogbo wọn lati maa gbe.

 
Ijọba ipinlẹ naa labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bẹrẹ igbesẹ lati maa ba awọn alẹnulọrọ, ẹgbẹ ṣe ipade nipa bi awọn olukọ yoo ṣe jẹ anfaani.
 
AWIKONKO gbọ pe ipade naa bẹrẹ pẹlu ẹgbẹ awọn olukọ, iyẹn Nigerian Union of Teachers (NUT), ẹka ti ipinlẹ naa, nibi ti wọn ti ṣalaye awọn erongba wọn fun wọn.

Gbọngan ileeṣẹ to n ri sọrọ ile-igbe ati idagbasoke igberiko (Ministry of Housing and Urban Development) ni ipade ọhun ti waye laipẹ yii, nibi ti awọn alakoso ẹgbẹ olukọ ti sọ awọn ohun ti wọn n fẹ ninu eto naa, eyi ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ pata yoo jẹ anfaani rẹ.

Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna ileeṣẹ naa, Ayaworan-ile Aliyu Muhammad Saifuddeen, sọ pe o pọn dandan f'awọn lati b'awọn ṣe ipade ko to di pe wọn bẹrẹ kikọ awọn ile naa lasiko, nitori pe wọn ko fẹẹ ṣe ojusaaju ẹnikẹni.

Bakan naa ni Saifuddeen sọ pe ki awọn alakoso ẹgbẹ naa lo kọ orukọ awọn olukọ patapata ti wọn wa labẹ ẹgbẹ wọn wa, lati le mọ iye ile-igbe ti wọn fẹẹ kọ.
 
Lara awọn to wa nibẹ ni akọwe agba nileeṣẹ naa, Hajia Afusat Nike Ibrahim; Alakoso agba fun ileeṣẹ Housing Corporation, TPL Giwa Mohammed; Alakoso ileeṣẹ Finance and Supply, Ọmọwe (Arabinrin) Idowu Bọsẹde Anu; Aalakoso agba nileeṣẹ to n ri sọrọ ile kikọ, Mallam Abioye Tunde Zarumi, at'awọn alẹnulọrọ miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI