Awa adari ati oloṣelu la ṣakoba fun ilọsiwaju ati idagbasoke Naijiria - Ibikunle Amosun jẹwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 10, 2022

Awa adari ati oloṣelu la ṣakoba fun ilọsiwaju ati idagbasoke Naijiria - Ibikunle Amosun jẹwọ


Gomina ana n'ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun ti sọ ọ sita gbangba wi pe awọn adari lorileede Naijiria ni wọn ṣakoba fun ilọsiwaju ati idagbasoke orileede yii, latari iwa imọtara-ẹni nikan.

Ibikunle Amosun to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja lo sọrọ naa laaaro oni, ọjọ Aje, Mọnde nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC YORUBA.

O ni nigba toun lọ kawe loke okun, oun rii pe awọn ilu ti wọn n darukọ wi pe wọn ṣẹṣẹ n dagba lẹyin Naijiria lakoko naa ni wọn ti fi orileede yii silẹ sẹyin, ti wọn si ti dagba soke kọja sisọ.

"Bo tilẹ jẹ pe ibi ti a lero wi pe ki ilu wa ti de, a ko tii debẹ, Bi Oluwa ba ṣe nnkan fun ẹda, ti ko ba tiẹ tii ti nnkan ti o lero, afi ko ṣ'ọpẹ. Bi a ba wa mu ni ti ọrọ orileede wa Naijiria, aye ọpẹ wa naa pọ.

"Bo tilẹ jẹ pe ibi to yẹ ka ti de, afi ti a ba maa tan ara wa jẹ, a ko tii debẹ rara, amọṣa, a ti wa lọna, ṣe lo yẹ ka tun dupẹ fun Oluwa wi pe ominira ni, ka si dunnu pe ominira ni, nitori pe bi a ba wo o l'ọtun, l'osi, gbogbo wa naa la n kọminu sii wi pe ki lo n ṣẹlẹ niluu wa yii.

"Wọn pa wọn nibi lonii, wọn pa wọn nibi l'ọla, eto aabo ti gbogbo ẹ mẹhẹ yii lo jẹ ka maa wo o wi pe a ko tii de ibi to yẹ, eyi to le jẹ ka maa ṣajọyọ orileede wa, amọṣa afi ka ṣe e.

"Bi a ba fẹẹ sọrọ sibi ti ọrọ wa, a maa rii wi pe bi Naijiria ṣe ri nigba yẹn kọ lo ri lasiko yii, idagbasoke diẹ ti wa, ṣugbọn ṣa o yẹ ko ti ju ibi to wa yii lọ, a si mọ pe Oluwa maa ba wa gbe e soke  debẹ."


Siwaju sii lo tun jẹ ko di mimọ pe gbogbo ipo ti Naijiria wa lonii kii ṣe amuwa Ọlọrun, bi ko ṣe afọwọfa awọn adari, to si jẹ ko ye awọn eeyan pe awọn adari lo fa a.

"Kii ṣe amuwa Ọlọrun lo fa ipo ti a wa yii, afọwọfa wa ni. A gbọdọ sọ ọ bo ṣe ri. Awa nikan kọ. Nigba ti wọn da Naijiria silẹ, wọn da awọn ilu miran silẹ lasiko yẹn naa. Awọn ilu naa lo si ti kọja wa gan-an ni, iyẹn lo maa fi han wa wi pe afọwọfa wa ni, kii ṣe amuwa Ọlọrun.

"Ọlọrun tiẹ nifẹẹ wa gan-an ni, n'igba ti mo n kawe niluu oyinbo,  wọn maa n pe awọn orileede kan wi pe awọn orileede ti wọn ti n bọ lọna, ti wọn si fẹẹ di orileede gbajugbaja, eyi ti wọn n pe ni 'Emerging Market, Emerging Nation'. Awọn ilu ti wọn n ka mọ wa nigba yẹn, wọn ti fi wa silẹ lọ gan-an bayii.

"Bi a ba maa ka wọn, wọn a maa ka India, Malaysia, Indonesia ati bẹẹbẹẹlọ ni wọno ti kọja wa, iyẹn ni mo fi mọ wi pe afọwọfa ara wa ni, kii ṣe amuwa Ọlọrun. Mo tiẹ fẹẹ le sọ pe Ọlọrun nifẹẹ wa ni orileede Naijiria, lo fi jẹ pe ibi ti a tiẹ ṣi le gbe e de yii, Ọlọrun nifẹẹ wa ni, ko rọgbọ rara.

"Mo si fẹẹ sọ oju abẹ nikoo wi pe ẹbi yii, lọdọ awa ti a jẹ olori ati oloṣelu ni. Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe oloṣelu lo ti n ṣe e lati bi ọgọta ọdun le meji ti a n sọ yii, ṣugbọn ẹ maa rii pe oloṣelu naa ti ṣe ninu ẹ. Awọn ologun ṣe, awọn alagbada naa ti ṣe.

"Ṣugbọn bi a ba wo gbogbo ẹ papọ, a maa rii wi pe pupọ ninu ẹ, awa oloṣelu lo ba wi, nitori pe awa naa la sọ pe a ko fẹ ologun mọ Nigba ti awa naa ti wa debẹ, awa lo yẹ ka ṣee ju bo ṣe wa yii lọ, amọṣa, a ti wa lẹnu ẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI