Jacob Zuma, aarẹ ilẹ South Afrika tẹlẹ ti jade l'ẹwọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, October 8, 2022

Jacob Zuma, aarẹ ilẹ South Afrika tẹlẹ ti jade l'ẹwọn


Ijọba ilẹ South Afrika ti fi aarẹ wọn tẹlẹri, Jacob Zuma silẹ l'ẹwọn lẹyin ti akoko rẹ ti wọn da fun un ti pe e.
 
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii ni ijọba ilẹ South Afrika kede sita wi pe awọn ti fi aarẹ wọn tẹlẹ naa silẹ lẹwọn, lẹyin ti ọjọ ti wọn da fun un ti pe.
 
Bakan naa ni awọn alakoso ọgba ẹwọn ti aarẹ Zuma wa naa sọ pe ko si lọdọ awọn mọ, nitori pe asiko to yẹ ko lo ti pe lọdọ wọn.
 
Nigba toun naa n jẹri si ominira rẹ, Zuma sọ pe inu oun dun lati tun jade sita pada layọ alaafia, ati lati le ṣe nnkan to ba tun wu oun.
 
O wa dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ fun aduroti wọn, ati diduro lori otitọ awọn nnkan toun n sọ. Bẹẹ lo ṣapejuwe bo ṣe jade naa si ti igba to jade lẹwọn Robben Island l'ọdun 1973, lakoko ti wọn ju oun pẹlu Nelson Mandela s'ẹwọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI