Awọn aṣeyọri Tinubu ati ipa rere rẹ lorileede Naijiria tito lati yan-an s'ipo Aarẹ - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 19, 2022

Awọn aṣeyọri Tinubu ati ipa rere rẹ lorileede Naijiria tito lati yan-an s'ipo Aarẹ - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe awọn aṣeyọri ti oludije s'ipo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti ko ninu idagbasoke orileede yii tito lati dibo fun un gẹgẹ bi aarẹ.
 
AbdulRazaq tun sọ siwaju pe koda, awọn ipa rere rẹ gan-an ko ṣee gboju fo da, nitori pe adari kan ṣoṣo to ju igba adari lọ ni Tinubu, ti yoo si gbe orileede Naijiria de ilẹ ileri.
 
O ni akọsilẹ aṣeyọri Tinubu lati ko awọn ikọ jọ tito lati yan an gẹgẹ bi aarẹ ilẹ Naijiria lọdun 2023.

AbdulRazaq sọrọ yii nibi ifilọlẹ ẹgbẹ YASIN fun ipolongo idibo aarẹ Tinubu/Shettima ati AbdulRazaq/Alabi fun ipo gomina lọdun 2023, eyi ti Alaaji Najeem Yasin to jẹ igbakeji aarẹ ẹgbẹ Nigerian Labour Congress (NLC) ṣagbatẹru ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI