Tirela ti ẹ n wo yii la gbọ pe awọn kan jigbe niluu Ijẹbu-Ode, ipinlẹ Ogun, ṣugbọn to jẹ iyalẹnu nla wi pe ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ni wọn ti pada rii.
A gbọ pe ṣe ni wọn gbe tirela naa si ẹgbẹ opopona ni agbegbe kan ti a fi orukọ bo laṣiri.
Wọn ni awọn ti iroyin naa ti kan si nipa wi pe wọn n wa tirela ọhun la gbọ pe wọn lọ ta awọn ọlọpaa lolobo nipa ẹ.
Ni kete tawọn ọlọpaa gbọ, ni wọn ti sare lọ sibẹ, ti a si gbọ pe fun bi ọpọlọpọ wakati ni wọn fi duro ti tirela ọhun, lati wo o boya awọn to gbe e sibẹ maa wa lati gbe e kuro, ṣugbọn ti ko sẹni to yọju sibẹ.
Lẹyin ti ko sẹni to yọju ni wọn l'awọn ọlọpaa wọ ọ lọ si teṣan wọn, ti wọn si ti ranṣẹ si ẹni to nii lati yọju.
Wọn ni ko si okuta kankan ninu ẹ mọ, koda ti wọn tun ti yọ taya mẹrin kuro l'ẹsẹ ẹ.
No comments:
Post a Comment