Baba agbalagba to n ko ibasun f'ọmọ rẹ l'Ogun dero atimọle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 7, 2022

Baba agbalagba to n ko ibasun f'ọmọ rẹ l'Ogun dero atimọle


Ọwọ ileeṣẹ eleto aabo n'ipinlẹ Ogun ti a mọ si So Safe Corps ti tẹ baba agbalagba, ẹni aadọta ọdun, Olukayọde Joseph to n ko ibasun f'ọmọ bibi inu ẹ, ọmọ ọdun mẹrinla.
 
A gbọ pe ṣe ni Olukayọde sọ pe ọmọ rẹ di maṣiini ibasun, to si n f'ojoojumọ ko ibasun fun un karakara, lai wo o pe ọmọ rẹ lo jẹ.
 
Ọjọbọ, Tọside, ana ni ọwọ palaba ọkunrin naa segi ni Akinbọ Phase 2 to wa ladojukọ ile Ọla Fatai, Ọlambẹ, ijọba ibilẹ Ifọ, ipinlẹ Ogun, lẹyin ti aṣiri rẹ tu sita.
 
Nigba to n gbe ọrọ naa si wa leti, agbẹnusọ fun ileeṣẹ So-Safe Corps, Mọruf Yusuf sọ pe o pẹ ti Olukayọde ti n ba ọmọ rẹ lajọsepọ, to si ni ko gbọdọ sọ f'ẹnikẹni, ati pe oun yoo pa a ni bi aṣiri naa ba tu sita.
 
Yusuf ni awọn oṣiṣẹ wọn to wa ni agbegbe Oke-Aro si Ọlambẹ, eyi ti SC Akeem Ọlaiya jẹ olori wọn lo rọwọ to Olukayọde.
 
O jẹ ko di mimọ pe awọn araalu ti n dana iya fun ọkunrin naa lakoko ti aṣiri rẹ tu, ṣugbọn to ni awọn oṣiṣẹ wọn lo sare debẹ lati gba a silẹ lọwọ iku ojiji, nitori pe diẹ lo ku ki wọn lu pa.
 
Ninu iwadii wọn lo ti jẹ ka mọ pe ọkunrin naa ti jẹwọ pe lotitọ ni, ati pe ko si b'oun ṣe fẹẹ bo aṣiri naa, to si lo n bẹbẹ fun oju aanu.
 
Bẹẹ lo jẹ ko ye wa pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ lati tubọ tẹsiwaju iwadii

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI