Wọn ju Rafiu sẹwọn oṣu mẹfa, ilegbee awọn akẹkọọbinrin lo lọ ja l'Oṣogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 7, 2022

Wọn ju Rafiu sẹwọn oṣu mẹfa, ilegbee awọn akẹkọọbinrin lo lọ ja l'Oṣogbo


Ile ẹjọ majisireeti to wa niluu Oṣogbo ti ju gendekunrin, ọmọ ọdun mẹrinlelogun kan, Rafiu Shuaibi sẹwọn ọsu mẹfa gbako, pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun ole jija.
 
Ilegbee awọn akẹkọọ ti wọn jẹ obinrin ti a mọ si female hostel la gbọ pe Rafiu lọ ja l'ọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan-an to kọja, ti ọwọ palaba rẹ si segi.

Agbefọba Fatọba Temitọpẹ to f'ẹsun kan Rafiu niwaju ile ẹjọ sọ pe ilegbee awọn akẹkọọbinrin ti fasiti Fountain, eyi to wa lagbegbe Oke-Ọṣun niluu Oṣogbo lo lọ ja, to si ji foonu ati owo nibẹ.
 
Foonu Itel, Power Bank, Earpiece, eyi ti owo gbogbo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira ni Rafiu ji ko salọ. Gbogbo awọn nnkan wọnyi ni wọn lo jẹ ti akẹkọọbinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Auolat Sule.
 
Nnkan bi aago marun aaro ni wọn lo gba ferese yara ọmọbinrin naa wọle, to si ji awọn dukia naa ko.
 
Awọn to fura la gbọ pe wọn pariwo sita, to si gba oju ferese naa jade lati salọ, ko to di pe wọn sare tẹlee lẹyin, ti wọn si rii mu.
 
Ẹsun ti wọn ka si Rafiu lẹsẹ yii la gbọ pe o tako iwe ofin ọdaran ti abala 411 ati 390 (9) Cap 34 Vol. II, ipinlẹ Ọṣun ti ọdun 2002.
 
Bo tilẹ jẹ pe Rafiu bẹbẹ pe iṣẹ eṣu ni, ati pe lotitọ loun jẹbi ẹsun naa, ki ile-ẹjọ f'oju aanu wo oun.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ A.O. Odeleye paṣẹ pe ki Rafiu lọ fi ẹwọn oṣu mẹfa gbako gbara, tabi ko lọ san ẹgbẹrun lọna ogun naira, gẹgẹ bi owo itanran, bi ko ba fẹẹ lọ sẹwọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI