Ẹgbẹ oṣelu APC l'awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ to tako Oyetọla gẹgẹ bi oludije s'ipo gomina lẹẹkeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 3, 2022

Ẹgbẹ oṣelu APC l'awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ to tako Oyetọla gẹgẹ bi oludije s'ipo gomina lẹẹkeji


Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), n'ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Gboyega Famọdun, ti gba gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa, paapaa awọn ọmọ ẹyin Gomina Adegboyega Oyetọla lamọran lati lọ fi ọkan wọn balẹ, nitori pe ejọ ko tii pari ni kootu.

O ni ki ẹnikẹni ma ṣe ronu nipa idajọ ile ẹjọ giga tiluu Abuja, eyi to sọ pe Gomina Oyetọla ko lẹtọọ lati jẹ ọmọ oye fun ẹgbẹ naa ninu idibo to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, ọdun yii.

Bẹ o ba gbagbe, ile ẹjọ giga lo gbe idajọ kalẹ wi pe bi wọn ṣe yan Oyetọla ati igbakeji rẹ, Benedict Alabi gẹgẹ bi ọmọ oye lati du ipo gomina ati igbakeji labẹ akoso Gomina Mai Buni, to fi orukọ awon mejeeji ranṣẹ si ajọ eleto idibo, Independent National Electoral Commission (INEC) tapa si iwe ofin orileede Naijiria.

Buni, gẹgẹ bi ile ẹjọ naa ṣe sọ, o tapa si abala 183 ninu iwe ofin orileede Naijiria, ati abala 82(3), ninu iwe ofin eto idibo, tọdun 2022.

Nigba to n tako idajọ naa, alaga naa lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Kọla Ọlabisi, o ni ẹgbẹ oṣelu alatako, iyẹn Peoples Democratic Party (PDP) ni wọn n da nnkan ru fun ẹgbẹ APC, ti wọn si fẹẹ ko wọn wahala.

O ni wọn fẹẹ da nnkan ru, niwọn igba ti wọn ti mọ pe igbẹjọ to n lọ lọwọ nile ẹjọ Tribuna to wa niluu Oṣogbo ti n ṣe ẹnu ire fun ẹgbẹ APC, to si ni PDP ti rii pe awọn ko le rọwọ mu.

Famọdun sọ pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lati tako idajọ naa laipẹ, to si ni ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ lọ fi ọkan wọn balẹ si idajọ to waye naa, nitori pe otitọ yoo foju han laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI