Idi ti wọn fi n pariwo Tinubu lasiko yii ree - Ọyalọwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, October 4, 2022

Idi ti wọn fi n pariwo Tinubu lasiko yii ree - Ọyalọwọ


Ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC, Ayọ Ọyalọwọ, ti sọ pe ko si nnkan meji t'awọn eeyan fi n pariwo nipa ilera oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, bi ko ṣe pe oun nikan lo kaju oṣuwọn lati di aarẹ.
 
Ọyalọwọ sọ pe digbi lara ọta Aṣiwaju Tinubu le koko lati dari orileede yii gẹgẹ bi aarẹ, ti ko si si nnkan to le ṣẹlẹ to ba de ipo naa l'ọdun 2023.
 
Lakoko to n sọrọ lori eto Politics Today nileeṣẹ tẹlifiṣan Channels l'ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.
 
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Tinubu funra rẹ gbe fọnran rẹ jade nibi to ti n ṣe ere idaraya lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe koko lara oun le, toun ko si ṣaisan kankan, iyẹn lẹyin ti iroyin jade sita wi pe ara rẹ ko ya gidi.
 
O tẹsiwaju pe gbogbo igba ni Tinubu yoo maa wa ninu iroyin nitori pe ọkan pataki lara awọn oludije s'ipo aarẹ, ti awọn alatako yooku n bẹru ni.
 
“Mo ti sọ nibi kan lọjọ diẹ sẹyin pe ọrọ Tinubu nikan ni wọn n sọ kaakiri. Fun idi eyi, ko si nnkan ti ọkunrin naa ṣe ti ko nii si ninu iroyin. Awọn kan tiẹ tun lọ ṣe ayidayida fọto fọnran to gbe sori ikanni ayelujara lori kẹkẹ nibi to le de.
 
“Aṣiwaju nikan ni pataki, ọkan pataki ninu eto idibo to n bọ lọna yii. Awọn eeyan yoo sọ ohunkohun ti wọn ba fẹẹ sọ, ṣugbọn o ye awa wi pe baba nilo lati sinmi daadaa nitori pe o ti ṣe wahala pupọ lẹnu ọjọ mẹta yii.
 
“O nilo lati fun ara rẹ ni isinmi nitori ipolongo ọlọjọ gbọọrọ ni eyi to n bọ yii yoo jẹ; a ni oṣu bii mẹrin fun ipolongo ko to di pe idibo apapọ waye. Fun idi eyi, o nilo lati fun ara nisinmi daadaa ko maa ba a ṣe ara rẹ leṣe.
 
“Ju gbogbo rẹ lọ, ọkunrin naa nilo lati sọ fun gbogbo eeyan pe ara oun ya daadaa. Wọn sọ pe o wa lọsibitu; awọn kan tiẹ sọ pe o ti ku. Oriṣiriṣi ọrọ radarada ni wọn ti sọ nipa Tinubu.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI