Ọrọ Yoruba kan ti wọn maa n sọ wi pe ko si bi a o ti se ebolo ti ko nii run igbẹ, bẹẹ gẹlẹ lọrọ Ganiyu Maruf ti ọwọ ẹṣọ aabo Amọtẹkun tẹ nipinlẹ Ọyọ pẹlu ori oku laipẹ yii ri.
Ni nnkan bi oṣu mẹta sẹyin la gbọ pe ọwọ ọlọpaa tẹ Ganiyu pẹlu awọn kan, lori ẹsun wi pe wọn n ta ori oku.
Lẹyin iwadii la gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa f'oju oun at'awọn tọwọ tẹ ba ile ẹjọ, ṣugbọn ti ile ẹjọ paṣẹ pe ki wọn ma beeli wọn, ki wọn si maa gba ile wa jẹjọ.
Ko pẹ si asiko naa la gbọ pe o tun pada lati lọ ra ori oku, ti ọwọ palaba rẹ si segi. Awọn ara agbegbe ti wọn ti fẹẹ lọ gbe ori oku lo rọwọ to wọn, ko to di pe awọn Amọtẹkun debẹ lati gba a silẹ.
Nigba to n sọrọ, Ganiyu sọ pe “Ko to di pe ọwọ Amotẹkun tẹ mi, Alaaji Adura, Kajọla ati emi la lọ ra ori oku lọwọ ọkunrin kan niluu Ọyọ, Dauda lorukọ ẹ, wọn si tun n pe e ni Baba To. Igba akọkọ ti maa ra ori oku lọwọ ẹ niyẹn ko to di pe aṣiri tu.
“Lọjọ ti mo ra ori oku meji naa lọwọ Dauda ni mo gbọ pe ọwọ ti tẹ ẹ. Ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni mo ra a. Loju ẹsẹ ni mo pe Aafa Basit wi pe ko tete lọ tọju ori oku naa. Niṣe la jọ da ẹgbẹrun lọna ọgbọn naa lọgbọọgba ti a fi ra ori oku naa ni, pẹlu erongba lati fi ṣoogun owo.
“Ẹgbọn Dauda to jẹ obinrin lo fẹ baba mi, ọdọ ẹ ni mo ti gburo iṣẹ to n ṣe. Mo sọ fun un pe ori oku meji ni mo fẹ, o si ta a fun mi.
“Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti tẹ oun naa ri. Ẹlẹẹkeji tọwọ maa tẹ ẹ, oṣu mẹta sẹyin ni, oun lo wa darukọ Alaaji Kajọla, Alaaji Kajọla lo darukọ Alaaji Adura, ko to di pe Alaaji Adura darukọ mi gẹgẹ bi ọkan lara awọn to ra ori oku naa lọwọ Dauda.
“Ko to di pe ọwọ tẹ mi, mo ti sare lọ tọju awọn ori naa sọwọ Basit. Awa mẹtẹẹta ni wọn foju wa ba ile ẹjọ, ti wọn si ti wa mọ ọgba ẹwọn. Adajọ pada fun wa ni anfaani beeli ni nnkan bi oṣu kan sẹyin.
“Mo gbọ pe wọn gba beeli Dauda naa, ko si le lọ si kọọtu mọ. Oju oorun lo ku si lọjọ keji ti wọn fi silẹ. Nigba ti mo dele, Aafa Basit wa ki mi lati dupẹ lọwọ mi, wi pe mi o darukọ oun mọ awọn tọwọ tẹ ẹ.
“Oun lo wa sọ ibi to lọ tọju awọn ori oku naa si. Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ to kọja ni mo lọ gbe e wi pe ka jọ lọ. Ibi ti a ti n lọ lawọn ara adugbo ti yọ si wa wi pe awa la maa n wa tọju ori oku si adugbo awọn.
“A ko kọkọ jẹwọ, ṣugbọn wọ bẹrẹ sii lu wa. Ọkan lara wọn ṣa mi ladaa lori ko to di pe awọn Amọtẹkun wa ko wa. Diẹ lo ku ki wọn pa wa.”
Maruf wa tẹsiwaju pe ọdọ baba iya oun loun ti kọ oogun owo ṣiṣẹ, nipa iwe toun jogun to pe ni 'Aṣiri ọla'.
Ọga awọn Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ọlayinka Ọlayanju, ti wa f'idi ẹ mulẹ pe wọn yoo tun pada f'oju ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
No comments:
Post a Comment