Gomina AbdulRazaq fi miliọnu mẹwàá naira ta idile Sheik Aboto to d'oloogbe lọrẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 7, 2022

Gomina AbdulRazaq fi miliọnu mẹwàá naira ta idile Sheik Aboto to d'oloogbe lọrẹ


Ṣe ni mọlẹbi Oloogbe Sheikh Abdulganiyu Aboto, ẹni to d'oloogbe l'ọsẹ to kọja yii ninu ijamba ọkọ bu sẹkun l'Ọjọbọ, Tọside to kọja yii nigba ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq kede sita wi pe oun fi miliọnu mẹwaa naira ta idile naa lọrẹ.

Nibi eto adura ọjọ kẹjọ ti wọn ṣe fun oloogbe naa, gbajugba oniwaasi nipinlẹ Kwara, eyi ti gomina naa lọ sibẹ lati kẹdun lo ti kede sita, to si lo di dandan f'oun lati ṣe iranwọ fun mọlẹbi oloogbe naa.
 
Yatọ si Gomina AbdulRazaq to wa nibi eto adura ọjọ kẹjọ fun oloogbe naa to waye ni Aboto-Alfa, ijọba ibilẹ Asa, awọn miran to tun wa nibẹ ni Khalifatul Adabiy Sheikh Abdulqodir Muhammad Kamaldeen; Grand Mufti tiluu Ilọri,n Sheikh Suleiman Faruq Onikijipa; Sheikh Ṣarafadeen Ajara; Jagunmolu ilu Igbaja ati alakoso ile-ẹkọ fasiti Al-Hikmah, Alaaji Ọladimeji Igbaja; aṣoju oludije sipo aṣofin laaarin gbungbun ipinlẹ Kwara, Sọliu Mustapha; Ọmọwe Abdullateef Adekilekun, at'awọn miran lo wa nibẹ.

Ṣaaju asiko yii ni Gomina ti fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ si mọlẹbi oloogbe naa, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi olotitọ oniwaasi ti ko fi igbakan bo ọkan ninu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI