Ọna ẹburu ni wọn fi yan Akinlade lati dije du ipo aṣoju-ṣofin agba lati Ogun - Ile-ẹjọ paṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 7, 2022

Ọna ẹburu ni wọn fi yan Akinlade lati dije du ipo aṣoju-ṣofin agba lati Ogun - Ile-ẹjọ paṣẹ


Ile ẹjọ giga apapọ to f'ikalẹ siluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe ọna ẹburu ni wọn gba yan Ọnarebu Isiaq Abiọdun Akinlade lati jade du ipo aṣoju-ṣofin agba l'ẹkun Yewa South ati Ipokia, labẹ asia ẹgbẹ All Progressives Congress, APC.

Onidajọ O.O Oguntoyinbo lo gbe idajọ naa kalẹ l'Ọjọbọ, Tọside to kọja yii, to si ni ọna ti wọn gba yan Ọnarebu Akinlade ko ba ofin ati ilana eto idibo, paapaa ofin ẹgbẹ oṣelu APC mu.
 
Ile ẹjọ sọ pe Akinlade ko ra fọọmu lati jade du ipo ti wọn n pariwo rẹ kaakiri, ati pe ko kopa ninu eto idibo abẹle to waye kọja, bẹẹ naa ni ko gba abẹ ayẹwo kankan kọja.
 
Fun idi eyi, ile ẹjọ naa tun paṣẹ pe ki ẹgbẹ oṣelu APC ṣagbekalẹ eto idibo abẹle miran laaarin ogoji ọjọ lati yan ọmọ oye ti yoo jade du ipo aṣoju-ṣofin agba l'ẹkun naa, iyẹn Yewa South ati Ipokia.
 
Siwaju sii ni ile-ẹjọ tun paṣẹ pe Akinlade ko gbọdọ kopa ninu eto idibo abẹle ti ẹgbẹ naa yoo tun ṣe, nitori pe ko yẹ lẹni to n ṣoju araalu.

Oloye Michael Adebayọ Adeleke lo pe ẹjọ naa lati tako bi wọn ṣe yan Isiaq Akinlade gẹgẹ bi ọmọ oye. Lara awọn to tun pe l'ẹjọ ni ẹgbẹ oṣelu APC, Isiaq Abiọdun Akinlade ati ajọ eleto idibo, Independent National Electoral Commission (INEC).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI