Lẹyin ọdun marun-un ati oṣu mẹfa: Wọn tu Ṣeun Ẹgbẹgbẹ silẹ l'ẹwọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, October 12, 2022

Lẹyin ọdun marun-un ati oṣu mẹfa: Wọn tu Ṣeun Ẹgbẹgbẹ silẹ l'ẹwọn


Iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ti f'idi rẹ mulẹ pe wọn ti tun gbajugbaja purodusa fiimu agbelewo, Ọlajide Kareem, ẹni t'ọpọ awọn eeyan mọ si Ṣeun Ẹgbẹgbẹ silẹ lahamọ awọn ọlọpaa to wa lati bi ọdun meji sẹyin.
 
Ọdun karun-un ati oṣu kẹfa ree ti Ṣeun Ẹgbẹgbẹ, ọkọ Toyin Aimakhu Ajeyẹmi, gbajugba oṣerebinrin nni ti ji foonu olowo nla loriṣiriṣi.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2016 ni wọn kọkọ mu ọkunrin naa lori ẹsun wi pe o ji foonu iPhone mẹsan ọtọọtọ l'Ekoo, ti wọon si f'oju rẹ ba ile-ẹjọ, ṣugbọn ti ile-ẹjọ pada gba beeli rẹ.
 
Ẹjọ naa lo n jẹ lọwọ, to tun lọ lu awọ Hausa to n ṣe owo ile okeere si ti Naijiria ni jibiti l'ọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2017, eyi gan-an lo tun mu ki wọn fi ẹsun tuntun kan an.
 
Lara ẹsun ti wọn fi kan an ni jibiti, alọnilọwọgba ati gbajuẹ, eyi ti wọn loo waye laaarin ọdun 2015 si ọdun 2017.
 
Wọn ni awọn to n ṣe owo naa, iyẹn Bureau De Change ti ko din ni ogoji lo lu ni jibiti laaarin ọdun naa.
 
Ṣeun Ẹgbẹgbẹ ati ọkan lara awọn ọmọṣẹ rẹ, Oyekan Ayọmide ni wọn jọ f'oju wọn ba ile-ẹjọ, niwaju Onidajọ Olurẹmi Oguntoyinbo, lọjọ kẹwaa, oṣu keji, ọdun 2017 lori ẹsun mẹrindinlogoji ọtọọtọ.
 
Ẹẹmeji ọtọtọ la gbọ pe wọn ṣe agbeyẹwo ẹsun ti wọn fi kan Ṣeun Ẹgbẹgbẹ, ti wọn si sọ ẹsun naa di ogoji, eyi to ni ijiya labẹ ofin.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana la gbọ pe ile ẹjọ giga apapọ to wa lagbegbe Ikoyi tun agbeyẹwo awọn ẹsun naa ṣe, ti wọn si rii pe ẹsun kan pere lo j'ẹbi rẹ, to si mu ki ile ẹjọ paṣẹ pe ki wọn fi silẹ.
 
Onidajọ Olurẹmi Oguntoyinbo nigba to n sọrọ sọ pe ẹsun mẹtalelogoji ninu ẹsun mẹrinlelogoji naa ni ko kun oju oṣuwọn to, nitori pe ko si ẹlẹri kankan fun wọn.
 
Ile ẹjọ naa sọ pe owo ti wọn gba lọwọ Ṣeun Ẹgbẹgbẹ l'awọn ọlọpaa naa lu jibiti ẹ, to si paṣẹ pe ki wọn da gbogbo owo ti wọn gba lọwọ ẹ pada fun un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI