Opin yoo deba aye familete-ki-n-tutọ t'awọn Iyalọja n jẹ l'Ekoo - Jandor - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 12, 2022

Opin yoo deba aye familete-ki-n-tutọ t'awọn Iyalọja n jẹ l'Ekoo - Jandor


Oludije s'ipo gomina ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Ọlajide Adediran ti ọpọ awọn eeyan mọ si Jandor ti sọ pe opin yoo de ba iwa ilọnilọwọ lati ọwọ iyalọja n'ipinlẹ naa.
 
O ni awọn ọlọja yoo bẹrẹ sii jẹ igbadun lasiko iṣakoso oun, to si rawọ ẹbẹ s'awọn araalu lati dibo f'oun ninu eto idibo to n bọ lọna yii.
 
Ninu atẹjade ti Jandor fi sita lonii, Ọjọru, Wẹsidee, o ni lasiko toun ba fi wa nipo gomina, ko nii si nnkan to n jẹ Iyalọja, to si ni aaye yoo wa fun eto ọrọ aje pẹlu ifọkanbalẹ.
 
Bakan naa lo sọ pe awọn ileri oun kii ṣe ohun ti ko le wa si imuṣẹ, to si ṣeleri ei pe oun yoo tubọ sọ awọn ipinnu oun sita fun ipinlẹ Eko laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI