Ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan niluu Orile Ilawọ to wa n'ijọba ibilẹ Ọdẹda, ipinlẹ Ogun, Ọba Alayeluwa Oluṣẹgun Alexander Macgregor ti sọ pe oun ti ṣetan lati tun itan ilu naa kọ nipa bi wọn yooṣe bẹrẹ sii yan ọba ati oloye niluu naa.
Olu Orile Ilawọ sọ pe bo tilẹ jẹ pe ijọba lo ni aṣẹ ati ẹtọ lati yan ọba fun wọn, nipa idibo t'awọn oloye to rọpo awọn afọbajẹ ṣe, ṣugbọn ṣa, awọn nilo lati wa lara awọn ilu ti wọn n lo ifa.
Kabiyesi naa lo sọrọ yii lakoko ipade to ṣe pẹlu awọn akọroyin nile ẹ to wa niluu Abẹokuta, nibi to ti yannayanna nipa aawọ to n waye lori ipo ọba ti wọn ṣẹṣẹ yan an si i.
Nibẹ lo ti sọ pe awọn to n gbe ayederu itan nipa iluu Orile Ilawọ kan n ṣe bẹẹ nitori ti wọn padanu lakoko idibo ni, kii ṣe nitori nnkan miran.
Kabiyesi sọ pe ojulowo ọmọ Ilawọ loun, to si ni awọn baba-nla oun wa lara awọn to tẹ ilu Ilawọ do lọdun 1800, ṣaaju ki wọn too da orileede Naijiria silẹ.
O ni ki ẹnikẹni to ba fẹẹ fi ẹhonu han lọ sile ẹjọ, nitori pe ijọba nikan lo lẹtọọ lati yan ọba tuntun siluu Ilawọ, ati pe ijọba lo ṣagbekalẹ ipo ọba naa lọdun 1999 si ọdun 2000.
"A ko gbe ade kankan wa lati ibikibi, a kii j'ọba tẹlẹ niluu Ilawọ, baba mi, Oloogbe Adebisi Macgregor to jẹ Olu Ilawọ ana ati Lisa ilu Ẹgba lo gbe igbesẹ bi wọn ṣe n jẹ ọba niluu Ilawọ, lasiko iṣakoso Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba gẹgẹ bii gomina.
"Asiko Ọtunba Gbenga Daniel gẹgẹ bii gomina ni ijọba bu ọwọ lu ọba fun wọn. Kii ṣe pe Ifa ni wọn da lasiko naa ti wọn fi yan Ọba Aina to waja l'oṣu kọkanla, ọdun 2021. Awọn to fẹẹ tun itan kọ, kan n ṣe bẹẹ lati fi da wahala silẹ ni.
"Aṣiṣe ti Ọba to waja naa ṣe ni pe ko gbe igbesẹ lori bi wọn yoo ṣe maa j'ọba, ati awọn idile to lẹtọọ lati j'ọba niluu Orile Ilawọ. Awọn nnkan wọnyi ni mo ṣetan lati ṣe. A si maa ṣe gesẹẹti lori ẹ laipẹ, ki ohun gbogbo le maa lọ bo ti yẹ.
"Lasiko ti a wa yii, Ifa ko tii ni nnkan ṣe pẹlu yiyan ọba fun ilu Orile Ilawọ, ijọba lo n yan an, nitori pe ijọba lo da jijẹ ọba silẹ. O digba ti a ba ni ofin, ka to le sọ pe ki Ifa maa tọ wa s'ọna."
No comments:
Post a Comment