O ma ṣe o! Ẹ wa gbọ nnkan ti Gomina AbdulRazaq sọ nipa gbajugbaja oniwaasi agbaye to jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 3, 2022

O ma ṣe o! Ẹ wa gbọ nnkan ti Gomina AbdulRazaq sọ nipa gbajugbaja oniwaasi agbaye to jade laye


Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe gbajugbaja oniwaasi agbaye kan, Sheikh Abdulganiy Dhu Nurayn Aboto al-Adaby ti jade laye l'ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja yii.
 
Sheik Abdulganiy, ẹni to f'iluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara ṣebugbe, at'awọn kan la gbọ pe wọn padanu ẹmi wọn sinu ijamba mọto lọjọ naa.

AWIKONKO gbọ pe odu ni oloogbe naa, kii ṣaimọ f'oloko ninu awọn agba oniwaasi to f'ilu Ilọrin ṣe ibugbe, nigba aye ẹ.

Nigba to n kẹdun iku oniwaasi naa at'awọn to padanu ẹmi wọn, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ olufọkansin tootọ, to ti imọ rẹ kọ awọn eeyan nilana ijọba ọrun.
 
AbdulRazaq sọ pe ibanujẹ nla ni iroyin iku agba ẹlẹsin naa jẹ fun ẹgbẹ ẹlẹsin Isilaamu, ati fun gbogbo ọmọ ilu Ilọrin lapapọ. O ni oloogbe naa fẹran ko maa gbe ẹsin Isilaamu larugẹ nipa awọn eto ọlọkan-jọ-kan.
 
O wa ba Ẹmir tilu Ilọrin,  Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari, mọlẹbi oloogbe atawọn ololufẹ, to fi mọ awọn ọmọlẹyin rẹ kẹdun, to si gbadura pe ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI