Ileeṣẹ Ọmọ Lamurudu gba awọọdu pataki nilẹ Yoruba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 3, 2022

Ileeṣẹ Ọmọ Lamurudu gba awọọdu pataki nilẹ Yoruba


Ṣe ni idunnu tun ṣubu lu ayọ awọn alaṣẹ ati alakoso ileeṣẹ kan to n gbe aṣa, iṣe ati ede Yoruba larugẹ kaakiri agbaye, ileeṣẹ Ọmọ Lamurudu Media n'igba ti ẹgbẹ ọdọ ilẹ Yoruba fi aami ẹyẹ da wọn lọla.
 
Ọjọ Aiku, Sannde, ana, ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ọdun ti a wa yii ni ẹgbẹ naa labẹ agboorun Yoruba Council of Youth Worldwide, ẹka t'ipinlẹ Ọyọ fi aami ẹyẹ naa da wọn lọla gẹgẹ Ọmọluabi Pataki to tayọ julọ, iyẹn Outstanding Ọmọluabi Pataki.
 
Alakoso ẹgbẹ naa n'ipinlẹ Ọyọ, Aṣoju Ọdọ Alawọde Akintunde Rahmon, nigba to n gbe aami ẹyẹ naa le oludasilẹ ileeṣẹ Ọmọ Lamurudu, Kọmureedi Ọmọọba Abiọdun Ismail, sọ pe kii ṣe pe wọn fi owo ra aami ẹyẹ ọhun, bi ko ṣe ti ipa rere ti wọn n kọ lawujọ ọdọ ilẹ Yoruba lo mu ki aami ẹyẹ ọhun tọ si wọn.
 
O ni atilẹyin ti ileeṣẹ naa n ṣe fun ẹgbẹ awọn kọja ohun ti wọn ko gbọdọ ma ṣe fi ẹmi imoore han si wọn, eyi to lo fa a ki wọn pinnu lati san oore ọjọ pipẹ.
 
 
 
Gbọngan igbalejo ti ile itura Ilaji Hotel and Sports Resort, to wa loju ọna Akanran niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ni wọn ti fi aami ẹyẹ naa da ileeṣẹ Ọmọ Lamurudu lọla nibi ayẹyẹ OYO STATE OMOLUABI PATAKI AWARD, akọkọ iru ẹ to waye.
 
Bakan naa, nigba toun naa n fi idunnu rẹ han, Ọmọọba Abiọdun Ismail sọ pe oun fi aami ẹyẹ naa sọri gbogbo ọmọ Yoruba atata to wa kaakiri agbaye, to si tun dupẹ lọwọ ẹgbẹ YCYW fun bi wọn ṣe ka ileeṣẹ wọn kun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI