Ọsibitu Oro nijọba ibilẹ Irẹpọdun ti fẹẹ pari - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, October 2, 2022

Ọsibitu Oro nijọba ibilẹ Irẹpọdun ti fẹẹ pari


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ọsibitu jẹnẹra ti ilu Oro to wa ni ijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ Kwara lati pari, ti awọn araalu yoo si bẹrẹ sii jẹ igbadun eto ilera igbalode.

Ipo ti atunkọ ati atunṣe ọsibitu ọhun wa bayii la gbọ pe o ti de ikarundinlaadọrun ko fi pari.

AWIKONKO rii gbọ pe ọsibitu naa ti dẹnukọlẹ patapata nigba ti iṣakoso yii maa gbajọba lọdun 2019.

Koda, wọn ni ilu miran to jinna si ijọba ibilẹ wọn l'awọn araalu ti lọ n gba itọju, nigbakugba ti wọn ba nilo itọju.

Ṣugbọn gbara ti Gomina AbddulRahman AbdulRazaq ti de ori aleefa lo ti bẹrẹ atunṣe ati atunkọ gbogbo awọn ileeṣẹ ijọba, to fi mọ ile ẹkọ ati ọsibitu si ti igbalode.

Agbaṣẹṣe ti atunkọ naa wa nikawọ rẹ, Theophilus Kuṣimọ nigba to n sọrọ jẹ ko ye awọn akọroyin pe ojuṣe ti ijọba n ṣe lo jẹ ki iṣẹ naa ya kankan, ati pe bi wọn yoo ba fi ri ọsẹ bii meloo si asiko yii, iṣẹ naa yoo pari patapata, ti yoo si di lilo araalu.Bi ọsibitu naa ṣe ri ati ipo to wa tẹlẹ ree:No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI