Owo Iṣowo: Awọn alagbata gbe oṣuba kare fun AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 6, 2022

Owo Iṣowo: Awọn alagbata gbe oṣuba kare fun AbdulRazaq


Ẹgbẹ awọn alagbata kaakiri Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori agbekalẹ owo iṣowo ti wọn fi ran awọn ọlọja kekeeke lọwọ kaakiri ipinlẹ naa.
 
Awọn alakoso ẹgbẹ naa ni wọn gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq lakoko ti wọn ṣe abẹwo idupẹ sii ni ileeṣẹ ijọba l'Ọjọru, Wẹside, ọsẹ yii, lati fi imọriri wọn han.
 
Nibẹ ni wọn ti ṣalaye pe ẹgbẹrun lọna ogun naira ti ijọba fun awọn ọlọja kekeeke naa ni ipa rere to ko nigbesi aye ẹnikọọkan wọn, to si ṣe anfaani fun imugbooro okoowo wọn.
 
Ẹgbẹ naa ti olori awọn Iyalọja n'ipinlẹ Kwara, Alaaja Sidikat Akaje, ati olori awọn babalọja, Alaaji Abdullahi Saheed, lewaju lọ ni wọn ti ko awọn eeyan wọn lẹyin lati dupẹ.

Alaaja Akaje, ninu ọrọ rẹ jẹ ko di mimọ pe miliọnu lọna ẹgbẹta ti ijọba pin f'awọn eeyan laipẹ yii fun awọn ọlọja ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn ko ipa rere ninu idagbasoke eto ọrọ aje, paapaa mọlẹbi awọn to jẹ anfaani naa.
 
O ni kii ṣe pe awọn wa ṣe nnkan miran, bi ko ṣe pe awọn wa fi ẹmi imoore han, nipa ọpẹ ati igboriyin fun Gomina to ka wọn kun, to si gbadura pe gomina wọn yoo ṣe saa ẹlẹẹkeji, nitori pe itan ti ko le parẹ titilai ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI