AbdulRazaq ati awọn ile-ẹkọ ti wọn dun un wo l'oju - Fafoluyi Ọlayinka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 6, 2022

AbdulRazaq ati awọn ile-ẹkọ ti wọn dun un wo l'oju - Fafoluyi Ọlayinka


Amugbalẹgbẹẹ pataki fun Gomina  AbdulRahman AbdulRazaq to ipinlẹ Kwara, Ọlayinka Michael Fafoluyi, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Solace lo ti kọ apilẹkọ ti ko wọpọ nipa ọga rẹ, ati bi atunṣe ba awọn ile-ẹkọ kaakiri ipinlẹ naa, eyi to mu ki idagbasoke de ba eto ẹkọ, ti ipinlẹ naa si n leke lẹka eto ẹkọ.

Ninu apilẹkọọ naa, eyi to pe ni 'AbdulRazaq and the new face of Public Schools in Kwara', lo ti jẹ ko di mimọ pe lati bi ọdun mẹrindinlogun sẹyin, eto ẹkọ ti dẹnukọlẹ patapata n'ipinlẹ Kwara, ti awọn iṣakoso ti wọn si n ni n'ipinlẹ naa ko rii ro rara.
 
O ni awọn araalu ko le tete gbagbe ipo ti eto ẹkọ wa n'ipinlẹ Kwara lati bi ọdun mẹrindinlogun sẹyin, nitori pe ajalu nla gidi to kọja oye ni eto ẹkọ foju winna rẹ, l'awọn asiko iṣakoso to ti kọja lọ.
 
"Bi eto ẹkọ ṣe dẹnukọla, naa ni aiwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ ko gbẹyin, ti awọn alakoso si n jaye familete-kin-tutọ pẹlu owo araalu, eyi ti ko bojumu to. Ati pe ṣe ni ipinlẹ naa n fi afẹfẹ oyinbo min nitori pe wọn ti mu gbogbo mudunmudun rẹ to n ṣe anfaani nla gbẹ lai ro ti awọn araalu

"Nigba ti ẹka eto ẹkọ, ati awọn ẹka yooku to wa labẹ iṣakoso ipinlẹ naa n sunkun wi pe awọn nilo atunṣe ati ayẹwo lakoko iṣakoso to kọja, awọn oloṣelu ti wọn ti kuna naa fun ọdun mẹrndinlogun n ko wo ibẹ, dipo bẹẹ, ṣe ni wọn n ṣe ajọyọ lati maa ṣe apapin owo ilu ni 'Ile Arugbo' fun awọn tọọgi, ọdaluru, atawọn miran labẹ wi pe wọn n ṣaanu awọn alaini. Wọn wa n ṣe bii Nero to n sun lakoko ti Roomu n jona.

"Ni gbogbo igba ti a ba n gbiyanju lati bojuwo iṣakoso ọdun mẹrirndinlogun ti PDP ṣe, o maa n fẹẹ dabi ẹni pe wọn fẹẹ da wa duro lati ṣe agbeyẹwo awọn igba naa, ṣugbọn ko to di pe a gbe igbesẹ naa, wọn a ti sare dide lati tako iṣakoso Gomina AbdulRazaq to n ji gbogbo ẹka iṣejọba to ti di oku dide, wọn a si maa da iṣakoso yii lẹbi awọn aṣiṣe ti awọn ti ṣe sẹyin. Ohun ti a nilo lati maa beere lọwọ ara wa ni pe ṣe ọdun merin to lati ṣe atunṣe awọn nnkan ti PDP ti bajẹ laaarin ọdun mẹrindinlogun sẹyin?

"Nigba ti Malaamu AbdulRahman AbdulRazaqmaa gba ijọba ninu oṣu karun-un, ọdun 2019, ipo ti ẹka eto ẹkọ wa wa ko ṣee ri rara, mo fẹẹ le sọ pe o ti di oku patapata, eyi to dabi ẹni pe ṣe la ṣẹṣẹ bẹrẹ eto ẹkọ nipinlẹ Kwara -- A nilo lati ṣe atunkọ gbogbo ile ẹkọ to ti fẹẹ wo lulẹ tan, ti a si tun kọ awọn tuntun miran -- eyi to jẹ moriwu f'awọn olukọ gbogbo.
 
Ẹ ka ẹkunrẹrẹ apilẹkọ naa nibi AbdulRazaq and the new face of Public Schools in Kwara

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI