Wolii Ayọdele fi mọto bọginni mẹwaa tọrẹ lọjọ kan ṣoṣo, o tun san owo ileewe akẹkọọ ọgọrun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, October 6, 2022

Wolii Ayọdele fi mọto bọginni mẹwaa tọrẹ lọjọ kan ṣoṣo, o tun san owo ileewe akẹkọọ ọgọrun


Idunnu nla lo ṣubu lu ayọ awọn eeyan ni ṣọọṣi INRI to jẹ ti Wolii Babatunde Elijah Ayọdele, nigba ti agba iranṣẹ Ọlọrun naa fi ẹbun nla tọrẹ fawọn ọmọ ijọ rẹ.

Nibi ayẹyẹ ayajọ ọjọ idupẹ ni Wolii Ayọdel ti fi ẹmi imoore han fawọn si Ọlọrun, to si ta awọn eeyan lọrẹ to kọja oye wọn.

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ kayeefi fawọn to jẹ anfaani, nitori pe ohun ti wọn ko lero tẹlẹ ni.

Fawọn to ba mọ Wolio Ayọdele daadaa, wọn yoo mọ pe ẹlẹyinju aanu to n fi ẹbun tọrẹ fawọn araalu ni, koda lai fi ti ẹsin tabi ẹya kankan ṣe.
 
AWIKONKO gbọ pe mọto mẹwaa, kẹkẹ maruwa mẹsan, ayẹwo oju ọfẹ f'awọnti ko din ni ẹẹdẹgbẹta, to fi mọ owo ileewe akẹkọọ ọgọrun-un ni Wolii Ayọdele fi ta awọn eeyan lọrẹ, nibi isin idupẹ ṣọọṣi naa, ẹlẹẹkẹta iru ẹ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI