Wọn layederu Akọgun wọ ilu Ilawọ l'Oke-Ọna Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 17, 2022

Wọn layederu Akọgun wọ ilu Ilawọ l'Oke-Ọna Abẹokuta


Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ l'opin ọsẹ to kọja yii ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe ijọba ipinlẹ Ogun ati Oṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Adewale Tẹjuoṣo tete gbe igbesẹ to yẹ, lati pana aawọ to n waye laaarin awọn oloye ilu Orile-Ilawọ niluu Abẹokuta, ipinlẹ naa.
 
Ilu Ilawọ lo wa labẹ Oke-Ọna Ẹgba ti Ọba Tẹjuoṣo jẹ olori ati alakoso wọn patapata.
 
Ohun ti a gbọ ni pe, ko si nnkan meji to n da wahala silẹ niluu Ilawọ naa, to kọja ọrọ ilẹ, eyi ti wọn lo mu k'awọn oloye ilu naa kẹyin sira wọn, koda to tun mu ki oloye bẹrẹ sii pe meji lori ipo kan ṣoṣo.
 
Lara wọn ni ti ipo Akọgun ilu Ilawọ ti wọn sọ pe Ọba Tẹjuoṣo ti yan ẹnikan l'ọdun 2016, ṣugbọn t'awọn oloye tun ditẹ lati yan ẹlomiran s'ipo naa l'ọdun yii lai gba aṣẹ lọwọ Ọba Tẹjuoṣo.
 
Oloye Wasiu Balogun la gbọ pe Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo fun ni iwe ẹri gẹgẹ bi Akọgun ilu Ilawọ l'ogunjọ, oṣu karun-un, ọdun 2016.
 
Ṣugbọn si iyalẹnu, a gbọ pe l'ọjọ kọkanlelogun, oṣu keje, ọdun yii l'awọn oloye ti Oluwo ilu naa, Oloye Samson Oluwọle Dosunmu lewaju wọn lati yan Ọgbẹni Lawrence Ogunsanya gẹgẹ bi Akọgun tuntun, eyi ti wọn ni ko ba ilana oye jijẹ n'ipinlẹ Ogun mu.
 
Ohun ti a gbọ ni pe ṣaaju asiko naa, ipo Apagunpọtẹ l'awọn oloye ilu naa sọ pe wọn fẹẹ fi Ogunsanya jẹ, ṣugbọn si iyalẹnu, wọn ni ọjọ iwuye naa ni wọn yi ipo ọhun si ipo Akọgun, to si ṣe ọpọ eeyan to wa nibẹ ni kayeefi.
 
Wọn ni ṣaaju akoko yii ni wọn ti pe Oloye Wasiu Balogun lori foonu wi pe awọn ti daa duro nitori awọn ẹsun ti wọn fi kan an, ti wọn si ni ọkunrin ko ka ọrọ ọhun si, ayafi igba ti wọn kede Ogunsanya gẹgẹ bi Akọgun Ilawọ.
 
Wọn ni gbogbo ipade t'awọn oloye n ṣe ni wọn pe Oloye Wasiu Balogun sibẹ, gẹgẹ bi Akọgun ilu naa, koda ti wọn fi pari gbogbo igbesẹ lati yan Akọgun miran, eyi ti wọn sọ pe ko han si Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo.
 
Latigba naa la gbọ pe awọn araalu ti n fi ẹhonu wọn han si iwa tawon oloye naa hu, eyi to mu ki wọn maa sọ pe bi ọba kan ko ku, ọba miran ko le jẹ, leyi to jẹ pe ayederu Akọgun ni wọn fẹẹ gbe le wọn lori ni tipatipa.
 
Wọn ni Akọgun to di ipo naa mu tẹlẹ ṣi wa laye, ko si tii sọ pe oun ko le jokoo lori ipo naa mọ, ati pe o digba ti Oloye Balogun ba jade lati sọ pe boya oun ko jẹ oye naa mọ, ki won too gba lati ri Lanrence Ogunsanya gẹgẹ bi Akọgun, ṣugbọn ni bayii, wọn ni ayederu lasan ni.
 
Ni kete ti wọn yan Ogunsanya la gbọ pe Oloye Wasiu Balogun ti kọ iwe ẹsun ranṣẹ si Ọba Tẹjuoṣo lati fi to kabiyesi leti, ṣugbọn ti a gbọ pe wọn ko ri esi kankan gba lati ọdọ kabiyesi lori ọrọ naa.
 
AWIKONKO gbọ pe ohun to tiẹ tun wa jẹ iyalẹnu bayii ni bi wọn ṣe sọ pe ipo ọba ilu naa to si silẹ lati inu oṣu kejila, ọdun 2021 ti Ọba Aina ti waja ni Lawrence tun n pariwo kaakiri bayii pe oun ni ipo naa tọ si.
 
Wọn ni ṣe ni Lawrence Ogunsanya n pariwo kaakiri pe oun ni ipo ọba naa kan nitori pe ipo nla loun di mu laaarin ilu, toun si lẹtọọ lati jẹ ọba, eyi ti wọn ni ko dun mọ puọ ninu awọn oloye naa, paapaa awọn araalu ninu.
 
Lati f'idi ọrọ naa mulẹ, AWIKONKO ba Osi ilu Ilawọ, Oloye Olufade sọrọ, ṣugbọn baba naa sọ pe oun ko le sọrọ, nitori toun ko si ni ipo ẹni to le sọrọ.
 
Oloye Olufade ninu ọrọ rẹ sọ pe “Bi ẹ ba fẹẹ gbọ ẹkunrẹrẹ ọrọ, inu mi yoo dun bi ẹ ba le ba Oluwo ilu Ilawọ sọrọ, nitori pe Osi ilu ni mo jẹ. Ipo mi kere si ẹni to le sọrọ, nnkan ti mi o ba si le lẹnu lati bura si, mi o ni fẹẹ ṣe e.”
 
Nigba to n b’AWIKONKO sọrọ, Oloye Wasiu Balogun sọ pe ipo Apagunpọtẹ ni wọn kede sita wi pe wọn fẹẹ fi Lawrence Ogunsanya jẹ, ṣugbọn to lo pada jẹ iyalẹnu wi pe ipo Akọgun toun di mu ni wọn gbe lee lọwọ lọjọ iwuye.
 
 O ni kayeefi gan-an lo tun jẹ pe ẹni ti wọn l'awọn gbe oye naa fun, ẹni toun mọ daadaa, to si mọ pe oun l'ẹni to di ipo naa mu ni, ṣugbọn toun naa ko kọ ipo ọhun.
 
Siwaju sii lo ni ko sẹni to le yọ oun n'ipo naa lai jẹ pe Ọba Tẹjuoṣo f'ọwọ si iwe, nitori pe kabiyesi naa lo fun oun ni iwe ẹri l'ọjọ toun jẹ oye naa.


“Mi o faramọ ẹni ti wọn yan si ipo ti mo di mu, nitori pe ohun ti mo tọwọ bọ iwe fun niwaju Ọṣile Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Tẹjuoṣo ni. Bi wọn ba maa sọ pe mi o kii ṣe Akọgun mọ, a jẹ pe Ọba Tẹjuoṣo lo maa sọ ọ sita gbangba wi pe awọn ko fẹ mi mọ.
 
“Ko s’ẹni ti ko mọ mi kaakiri igboro Abẹokuta yii gẹgẹ bi Akọgun ilu Ilawọ. Nigba ti mo gbọ nipa igbesẹ ti wọn n gbe, mo kọ iwe ẹsun si aafin Ọṣile lati fi to kabiyesi leti, mi o si tii gbọ nnkankan latigba naa. Mi o tii gbe igbesẹ miran lẹyin naa, nitori pe mo gba pe ẹni to ba fẹẹ lo ile aye pẹ, a fi ko ṣe jẹjẹ, ati pe mi o mọ ohun ti wọn ni lọkan si mi.
 
“To ba jẹ pe ẹni ti wọn l’awọn fi jẹ Akọgun yẹn kawe ni, o yẹ ko mọ pe bi ọba kan ko ku, ọba miran ko le jẹ. Ẹni yii si ree, ẹni ti mo mọ daadaa, ti a jọ maa n ṣe papọ ni, o wa ya mi lẹnu pe ẹni naa le tẹwọ gba iru ipo naa lọwọ wọn, nigba to mọ pe emi ni wọn n gbogun ti."
 
Gbogbo akitiyan lati ba Oluwo ilu Ilawọ ati Lawrence Ogunsanya sọrọ lo ja si pabo titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ti a si nigbagbọ pe bi wọn ba yọju si wa, a maa mu ọrọ ti wọn naa wa fun un yin.
 
Ju gbogbo rẹ lọ, ohun ti awọn araalu n sọ bayii ni pe ki wọn gba wọn lọwọ awọn oloye ti wọn ko jẹ ki alaafia ati irẹpọ wa niluu Ilawọ, nitori pe ọkan wọn ko balẹ pẹlu bi nnkan ṣe n lọ lasiko yii, ati pe awọn ko fẹ Lawrence Ogunsanya n’ipo Akọgun, depodepo ipo ọba to n pariwo rẹ kaakiri lasiko yii.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI