Adanu nla lẹgbẹ oṣelu APC jẹ fun Naijiria - Ayu pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 20, 2022

Adanu nla lẹgbẹ oṣelu APC jẹ fun Naijiria - Ayu pariwo sita


Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lapapọ, Iyorchia Ayu, ti sọ pe bi awọn ọmọ orileede Naijiria ba n fẹ ilọsiwaju ati idagbasoke fun orileede yii, afi ki wọn f'ibo le ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC danu.
 
Iyorchia Ayu ni gbogbo rogbodiyan, ijakulẹ ati rederede to de ba orileede yii ko ṣẹyin ẹgbẹ oṣelu APC, to si ni asiko ree lati le gbogbo wọn danu.
 
Ayu lo sọrọ naa nipinlẹ Ondo, nibi iwuye Eyitayọ Jẹgẹdẹ, gẹgẹ bii Balogun ijọ Saint David, iyẹn Cathedral Church of Saint David Ijomu Akurẹ.
 
Ayu, ẹni ti Sẹnetọ Sam Anyanwun ṣoju fun lo sọrọ naa jade, to si ni latigba ti ẹgbẹ APC ti gbajọba lọdun 2015 ni igbe-aye ti bẹrẹ sii le koko f'awọn ọmọ Naijiria.
 
O ni ọna kan ṣoṣo ti awọn ọmọ Naijiria le fi bọ ni lati paarọ wọn pẹlu ẹgbẹ miran ti wọn kaju ẹ lati tun orileede yii ṣe nipa ifẹ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI