Ajiki Olu, gbajugbaja puromota ro awon opo, akẹkọọ ẹgbẹ rẹ lagbara l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 4, 2022

Ajiki Olu, gbajugbaja puromota ro awon opo, akẹkọọ ẹgbẹ rẹ lagbara l'Abẹokuta


Gbajugbaja puromota olorin nni, Oloye Arẹmu Bamgboye ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ajiki Olu lo ti ro awọn opo ti wọn jọ lọ sileewe lagbara pẹlu owo ati awọn nkkan miran.

Ajiki Olu, ẹni to fi ilu Abẹokuta ṣe ibugbe la gbọ pe o ṣe ironilagbara yii lati fi ṣe iranwọ fawọn ti wọn jọ lọ sileewe girama ti Anglican yo wa lagbegbe Quarry niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, pupọ awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ ti wọn jọ lọ sileewe, paapaa awọn ti wọn jọ wa ni kilaasi laaarin ọdun 1995 si 1996 ni wọn sọ pe ọkunrin naa da lọla.

Nibi ipade ọlọdọọdun wọn tu wọn pe ni Re-Union ni wọn sọ pe gbajumọ puromota olorin naa ti da awọn eeyan ọhun lọla.

Ajiki Olu ti wọn fi jẹ aarẹ ẹgbẹ àwọn akẹkọọ ọdun 1995 si 1996 naa laipẹ yii nigba to n sọ erongba rẹ, o ni lara awọn ohun to wa ṣe nile aye ni lati maa ran awọn eeyan lọwọ.

O ni ọpọ awọn eeyan loun ti ran lọwọ, to jẹ pe wọn ti n ṣe rere laye lasiko yii, idi ree to fi loun ko le gbagbe awọn ti wọn jọ bẹrẹ lati kekere, paapaa nile ẹkọ.

Lara awọn to jẹ anfaani irolagbara naa sọ pe idunnu nla lo jẹ fawọn wi pe oore nla naa wọle tọ awọn wa, nitori pe ohun ti wọn ko ro tẹlẹ ni.

Ajiki ninu ọrọ rẹ, o ni "Nigba ti mo de ipo Aarẹ ẹgbẹ yii, mo jẹ ko ye awọn eeyan mi wi pe alaafia ati igbayegbadun wọn lo jẹ mi logun, paapaa awọn to jẹ opo laaarin wa.

"Ohun ti a n ṣe lonii jẹ ileri ti mo ṣe, ti mo si mu wa si imuṣẹ. A maa tubọ maa ran wa lọwọ lati fa ara wa de ibi giga."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI