Kwara 2023: Oludije sipo gomina labẹ asia SDP ati NNPP jawọ, wọn ba PDP lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 6, 2022

Kwara 2023: Oludije sipo gomina labẹ asia SDP ati NNPP jawọ, wọn ba PDP lọ


Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ti jẹ ko ye wa pe oludije s'ipo gomina n'ipinlẹ Kwara labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP ati oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu New Nigeria's People Party, NNPP, Ọjọgbọn ỌbaAbdulraheem ti kede wi pe awọn ti juwọ silẹ lati ṣagbatẹru f'ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
 
Wọn l'awọn ti ṣetan lati ṣagbatẹru oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Shuaib Yaman, ki wọn le rọwọ mu ninu eto idibo to n bọ lọna.

Ilu Abuja l'awọn oludije naa ti ṣe ipade ikọkọ lati fẹnuko, iyẹn l'Ọjọbọ, Tọside to kọja yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Ẹnikan to ta wa lolobo iroyin naa, ẹni to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri jẹ ko di mimọ pe nibi ipade naa ni wọn ti jọ tọwọ bọwe adehun, lori bi wọn yoo ṣe pin ipo oṣelu funra wọn, lẹyin ti wọn ba jawe olubori.

He said, “Ọba Abu ati Hakeem Lawal mọ daju pe awọn le wọle sibikibi ninu eto idibo to n bọ lọna yii, ati pe bi awọn ṣe yapa le fun AbdulRazaq lanfaani lati ijawe olubori. Wọn wa n wa ọna abayọ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI