Ajọ UNDP ṣeleri eto igbadun nla fun ipinlẹ Kwara, l'awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu SDP ba tun ya lọ APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 4, 2022

Ajọ UNDP ṣeleri eto igbadun nla fun ipinlẹ Kwara, l'awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu SDP ba tun ya lọ APC


Ajọ agbaye kan ti wọn pe ni United Nations Development Programme, UNDP ti ṣeleri eto aabo to peye fun ipinlẹ Kwara, lojuna lati jẹ ki awóon araalu maa sun pẹlu ifọkanbalẹ.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii ni aṣoju ajọ naa si orileede Naijiria, Mohamed Yahya fi idaniloju naa sita, wi pe awọn ti ṣetan lati ṣe iranwọ fun gbogbo araalu, nipa owo ati awọn nnkan amayedẹrun.

Nibi asọyepọ ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ati alaga ajọ naa, Yahya ṣe, o jẹ ko di mimọ pe awọn yoo ko owo kalẹ fun gbogbo awọn to ku diẹ kaato fun lati fi ṣe iranwọ fun ọṣẹ ti ajakalẹ arun korona ṣe f'awọn eeyan.

Ajọ UNDP jẹ ajọ aladani ti wọn n ṣe iranwọ f'awọn ijọba kaakiri, ati araalu.
 
 
 
Bakan naa ninu iroyin miran ti a gbọ, wọn ni ogunlọgọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP ti ya kuro lọ sinu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara.
 
A gbọ pe pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu SDP ti wọn fi erongba wọn han lati ṣoju n'ipinlẹ naa, ti wọn si kopa ninu idibo abẹle ẹgbẹ naa to waye kọja, ṣugbọn ti wọn padanu, ni wọn l'awọn ko le tẹsiwaju ninu ẹgbẹ naa mọ

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe ṣalaye, wọn ni ko si nnkan meji to mu k'awọn eeyan naa lọ fi atilẹyin wọn han fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, bi ko ṣe awọn ipa to ti ko ninu eto idagbasoke ipinlẹ naa, ati iranlọwọ f'awọn araalu loriṣiriṣi ẹka eto oṣelu.

Lara awọn to dije s'ipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lakoko idibo abẹle ẹgbẹ SDP, ti wọn lawọn ti ba AbdulRazaq lọ bayii ni Ahmed Kọla Akorede, Essa/Shawo/Igboidun Constituency, ijọba ibilẹ Ọffa; Abdulmajeed Dọlapọ, Balogun/Ojomu Constituency, ijọba ibilẹ Ọffa; ati Adeyẹmọ Olufunmilayọ, Magaji Ngeri Constituency, ijọba ibilẹ Ilọrin West.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI