Ijọba ni lati san owo 'gba ma binu' fun wa lori awọn ohun ọsin ti a padanu lọdun 2022 - PAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 2, 2022

Ijọba ni lati san owo 'gba ma binu' fun wa lori awọn ohun ọsin ti a padanu lọdun 2022 - PAN


Ẹgbẹ awọn olohun ọsin kaakiri orileede Naijiria, iyẹn Poultry Association of Nigeria, PAN ti rawọ ẹbẹ s'ijọba orileede yii lati san owo 'gba ma binu' fun lori awọn ohun ọsin ti wọn padanu lọdun 2022 to n kasẹ wọle yii.

Awọn adari ẹgbẹ naa ni wọn fi erongba wọn han nibi ipagọ ọlọdọọdun wọn ti wọn pe ni Nigerian Poultry Show (NPS 2022), eyi ti wọn pe akori rẹ ni "Sustaining The Nigerian Poultry Industry Amidst Global Economic Crisis", lo waye niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii.

Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe kolonka lawọn ohun ọsin ti wọn padanu lọdun 2022 ti a wa yii, nitori aarun onigba rẹpẹtẹ, iyẹn 'Birds Flu' to kọlu awọn nnkan ọsin wọn.

Alakoso ẹgbẹ naa l'ẹkun Iwọ Oorun orileede yii, Gideon Olulẹyẹ lo sọrọ naa sita lakoko to n b'awọn ọmọ ẹgbẹ naa sọrọ nipa awọn iṣoro ti wọn koju lọdun 2022.

Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe ajalu nla lo kọlu awọn ohun ọsin wọn nigba ti aarun to pe ni Avian Influenza, eyi ti wọn tun n pe ni Birds Flu wọle tọ wọn lọ.

Eto naa ni wọn n ṣe lọdọọdun naa, lati ṣagbeyẹwo awọn iṣoro to n koju wọn, ọna abayọ ati paapaa bi okoowo wọn yoo ṣe maa lọ siwaju sii. Yatọ si ẹran, awọn ohun ọsin bii adiẹ lo tun ni ohun elo aṣaraloore ti a mọ si Protein lara, to si dara pupọ fun jijẹ.

Nigba to n kọminu lori ọṣẹ ti ajakalẹ aarun korona ṣe fun wọn, eyi to jẹ ki wọn padanu rẹpẹtẹ, o ni bi ijọba apapọ ba le san owo gba ma binu f'awọn, eyi yoo jẹ ki wọn mọ pe ijọba n ṣe iranlọwọ to yẹ fun eto aabo wọn.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe eeyan ti ko din ni miliọnu marundinlọgbọn  ni iṣẹ agbẹ olohun ọsin ti pese iṣẹ fun kaakiri Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI