Aye o! John lu ololufẹ rẹ pa nitori owo Yahoo to gba lọwọ Oyinbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 30, 2022

Aye o! John lu ololufẹ rẹ pa nitori owo Yahoo to gba lọwọ Oyinbo


Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ gendekunrin, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Obeta John, ẹni to lu ololufẹ rẹ pa nitori ọrọ ti ko to nnkan, ti wọn sọ pe awọn mejeeji jọ n fa.

A gbọ pe ṣe ni John ti ololufẹ rẹ naa, Idowu Buhari mọ inu yara, to si bẹrẹ sii luu bi ẹni lu ilu bẹmbẹ, tiyẹn si gbabẹ ku mọ ọn lọwọ, iyẹn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe iṣẹ jibiti ori ayelujara ti a mọ si Yahoo-Yahoo ni John n ṣe niluu Ṣaapade, ti wọn si lo gbajumọ daadaa nibẹ.
 
Wọn ni ipele kẹta, HND1 ni ẹka ikẹkọọ iṣẹ iroyin ati igbohunsafẹfẹ ni ọmọbinrin naa wa nile ẹjọ gbogboniṣe ti imọ ayelujara ti ipinlẹ Ogun, iyẹn Gateway ICT Polytechnic to wa niluu Ṣaapade.
 
Ojule kẹta, adugbo Mojubade to wa lagbegbe Eredu, Iṣara Rẹmọ ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
AWIKONKO gbọ pe awọn ti John lu ni jibiti lori ayelujara lo fi owo ranṣẹ sii, ti a si gbọ pe apo owo ile ifowopamọ Idowu ni wọn fi owo naa ranṣẹ si, ṣugbọn ti wọn sọ pe ọmọbinrin naa fẹẹ gbẹsẹ lee.

Wọn ni ibi ti wọn ti jọ n fa ọrọ naa, ni John ti fibinu luu pa.
 
Ọpọ awọn to gbọ bi John ṣe n lu Idowu ni wọn n ba a bẹbẹ wi pe ko fi silẹ, ati pe awọn yoo ba wọn yanju ẹ, ṣugbọn ti ko gbọ si wọn lẹnu, igba ti wọn ni ọmọbinrin naa dakẹ loju rẹ too ṣẹṣẹ la.

Bi John ṣe rii pe Idowu ti dakẹ lo ti gbiyanju lati na papa bora, ṣugbọn ti wọn ko jẹ ko raaye salọ. Loju ẹsẹ ni wọn ti gbe Idowu lọ si ọsibitu lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ti awọn dokita sọ pe oku ni wọn gbe wa f'awọn.

Eyi lo jẹ ki wọn lọ fa John le awọn ọlọpaa Ode Rẹmọ lọwọ, ti wọn si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn.
 
Nigba ti wọn n fọrọ wa John, ọmọ bibi ipinlẹ Ẹnugu naa lẹnu wo, o sọ pe lotitọ loun n ṣe Yahoo-Yahoo, toun si n ri owo gidi nibẹ. O ni owo kan l'awọn onibara oun fi ranṣẹ si Idowu, ṣugbọn ti ko fẹẹ ko owo naa silẹ foun.
 
O ni ṣe ni Idowu sọ pe idi oun ti jẹ owo naa, ati pe ere loun kọkọ pe e, ṣugbọn boun ṣe rii pe kii ṣe awada, lo jẹ koun fibinu tilẹkun yara mọ ọn, toun si luu, bo tilẹ jẹ pe oun ko mọ pe yoo pada ku mọ oun lọwọ.
 
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lẹkunrẹrẹ nipa John, ki wọn si rii daju pe wọn foju rẹ ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI