Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara ti gbe iwe eto iṣuna ọdun 2023 lọ siwaju ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, eyi to ni biliọnu lọna igba din diẹ N189,436,248,054.00 naira l'awọn fẹẹ na.
Oni tii ṣe Ọjọru, Wẹsidee ni gomina gbe iwe aba eto iṣuna naa lọ siwaju awọn aṣofin lati ṣe agbeyẹwo rẹ, ko to di pe wọn bu ọwọ luu.
A gbọ pe ida aadọta le ni mẹsan, 50.9% ni wọn yoo fi bẹrẹ awọn akanṣẹ iṣẹ tuntun to nii ṣe pẹlu ara ilu, iyẹn Capital Component, nigba ti ida mọkandinlaadọta le ni ookan, 49.1% ni yoo ba awọn iṣẹ to n lọ lọwọ, iyẹn Recurrent Expenditure lọ.
Aba eto iṣuna naa ni gomina sọ pe yoo mu imugbooro ba eto ọrọ aje ati idagbasoke alailẹgbẹẹ ipinlẹ Kwara.
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe nipa iranlọwọ ile igbimọ aṣofin ati awọn eeyan ipinlẹ naa, ijọba oun ti mu ọpọ awọn ileri akoko eto idibo to kọja ṣẹ nipa eto ẹkọ, ilera, ipese omi ẹrọ igbalode, iṣẹ agbẹ, ẹdinku ba iṣẹ ati oṣi, igbayegbadun awọn oṣiṣẹ, akanṣe iṣẹ idagbasoke, to fi mọ idagbasoke agbegbe ati igberiko.
Ki lo wa ninu aba eto iṣuna naa? Aba Eto Iṣuna Kwara
No comments:
Post a Comment