Ẹ wo aragbayamuyamu ileeṣẹ ọlọpaa tijọba Kwara ṣi fawọn ọlọpaa n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, November 24, 2022

Ẹ wo aragbayamuyamu ileeṣẹ ọlọpaa tijọba Kwara ṣi fawọn ọlọpaa n'Ilọrin


Gomina AbddulRahman AbdulRazaq ti gbe oṣuba rabandẹ fawọn ọlọpaa lorileede Naijiria, paapaa awọn ti ipinlẹ Kwara lori ipa ti wọn n ko lori idagbasoke eto aabo.

AbdulRazaq ni ko si iye owo teeyan kan le na lati fi ran awọn ọlọpaa lọwọ lori iṣẹ ti wọn n ṣe, to le pọ ju, bi ko ṣe pe owo naa ko tun nii to.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii ni gomina ipinlẹ Kwara sọrọ naa jade niluu Ilọrin, nibi to ti ṣiṣọ loju eegun teṣan tuntun to jẹ ti awọn ọlọpaa.

Lara awọn to wa nibẹ ni ọga ọlọpaa pata lorileede Naijiria, Usman Alkali Baba; kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ naa, Paul Odama; amugbalẹgbẹẹ agba pataki fun gomina lori ọrọ eto  aabo, Aliyu Muyideen; Balogun ilu Ilọrin to ṣoju Ẹmir ilu Ilọrin, Ọmọwe Abubakar Usman Jos; at'awọn miran.

O ni bi eto aabo araalu ṣe jẹ ọlọpaa logun, naa lo yẹ ki ijọba, araalu ati gbogbo awọn ti ọrọ kan maa bojuto igbayegbadun awọn naa, ki iṣẹ wọn le tubọ maa tẹsiwaju.

O wa gbe oṣuba kare fun ọga ọlọpaa lorileede yii, fun awọn akitiyan rẹ lati maa wa gbogbo ọna ti yoo jẹ ki ọlọpaa mọ pataki iṣẹ ti wọn n ṣe fun ilu ati orileede wọn.

Opopona Madi ni aragbayamuyamu teṣan tuntun naa wa ni ijọba ibilẹ Ilọrin West, ipinlẹ Kwara.

AbdulRazaq ni idunnu nla lo jẹ foun lati rii pe ipinlẹ oun ni wọn kọ teṣan nla to ba ti igbalode mu naa si, to si tun lo jẹ iwuro nla foun.

O wa fi da awọn eeyan loju pe oun yoo gba awọn gomina ẹgbẹ oun lamọran nibi ipade awọn gomina to maa waye laipẹ yii lati tẹle iru apẹẹrẹ bayii.

Ọga ọlọpaa pata naa, Alkali ninu ọrọ rẹ dupẹ lọwọ gomina lori awọn atilẹyin ati iranlọwọ to n ṣe fun ileeṣẹ ọlọpaa loorekoore, bẹẹ lo si l'awọn n mọ riri rẹ daadaa.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI