Ọna kan ṣoṣo ti o le gba di ojulowo lanlọọdu n'ipinlẹ Ogun ni ibamu pẹlu ofin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, November 25, 2022

Ọna kan ṣoṣo ti o le gba di ojulowo lanlọọdu n'ipinlẹ Ogun ni ibamu pẹlu ofin


Oriṣiriṣi ileeṣẹ to n ta ile ati ilẹ lo wa kaakiri ipinlẹ Ogun, paapaa niluu Abẹokuta to jẹ olu-ilu ipinlẹ naa lasiko yii, to si jẹ pe onijibiti lo pọ ju laaarin wọn, ṣugbọn bi awọn ayederu ileeṣẹ ṣe wa, naa ni ojulowo wa.
 
Lara awọn to jẹ ojulowo ileeṣẹ to n ta ile ati ilẹ, ti wọn si tun ni ontẹ ijọba ninu ni ileeṣẹ PELICAN VALLEY NIGERIA LIMITED wa. Odu si ni wọn, wọn kii ṣaimọ f'oloko nipa ka ta ile ati ilẹ.
 

Pupọ awọn ileeṣẹ ti wọn n fi dukia bii ile ati ilẹ lu awọn araalu ni jibiti lo jẹ pe ori redio ati tẹlifiṣan ni wọn n gba lọ lati polowo. Lara awọn ẹtanjẹ ti wọn si fi n fa oju awọn alaimọkan mọra ni awọn nnkan ifa ti wọn fi n tan wọn.
 
Bi ẹ ba n gbọ ti wọn n sọ pe 'ẹ wa ra ilẹ, ki ẹ si gba irẹsi tabi ẹran agbo ọdun', ẹ tete fura si wọn, tabi ki ẹ ro o lẹẹmeji ko to di pe ẹ ba wọn dowopọ.
 
A ko sọ pe gbogbo awọn to n gbe iru anfaani yii kalẹ ni wọn jẹ oni jibiti o, ṣugbọn ṣa, pupọ wọn lo jẹ pe jibiti ni wọn n lu kaakiri, nipa ẹtanjẹ ti wọn n pariwo lori redio ati tẹlifiṣan.
 
Ṣugbọn bi o ba fẹẹ di lanlọọdu nipinlẹ Ogun pẹlu ifọkanbalẹ, ileeṣẹ Pelican Estate nikan lo le fi ọkan rẹ balẹ, nitori pe otitọ inu ni wọn fi n ṣe gbogbo ohun ti wọn n ṣe.
 

Ko si wahala ọmọ onilẹ lori ilẹ tabi ile ti wọn ba ta fun un yin, nitori pe gbogbo iwe ẹri ijọba to yẹ ni wọn ti gba, fun irọrun awọn onibara wọn.
 
N'ipinlẹ lonii, ọkan pataki lara awọn ileeṣẹ to jẹ ojulowo ileeṣẹ to n ṣowo dukia ni ileeṣẹ Pẹlican Estate jẹ, ti ẹri ati idaniloju si wa kaakiri, nitori pe otitọ inu ni wọn fi n ṣe.
 
Yatọ si pe wọn n ta ilẹ f'awọn eeyan, wọn tun n ba awọn onibara wọn kọ ile, pẹlu awọn ohun elo to jọju, lati ori bulọọku, simẹnti, okuta ati bẹẹbẹẹlọ, ko da to fi mọ awọn akọṣẹmọṣẹ birikila ọlọpọlọ pipe lo n ba wọn ṣiṣẹ.
 
Bi ẹ ṣe le ra ilẹ ati ile lẹẹkan naa, bẹẹ naa lẹ le maa san owo diẹdiẹ lọna ti ko nii pa yin lara. Bi ẹ ṣe le san owo laaarin oṣu mẹfa, naa lẹ le san owo laaarin ọdun kan.
 
Pelican Valley Nigeria Limited ni ọpọ eeka ilẹ si agbegbe Ẹgbẹda niluu Abẹokuta, eyi ti wọn pe ni Pelican Greenish Acres. Miliọnu mẹta aabọ ni eeka kan, bi ẹ ba si fẹẹ san owo rẹ diẹdiẹ, miliọnu kan naira lẹ maa kọkọ san, oṣu mẹfa lẹ si maa fi san eyi to ku.
 

Pelican Ecostay Apartments wa lagbegbe Masa, Kọbapẹ niluu Abẹokuta, nibi ti ẹ ti maa ra ile oni yara mẹta, iyẹn 3 Bedroom Duplex + BQ ni ọgọta miliọnu din diẹ (₦59.750m). Miliọnu marun-un naira  lẹ maa kọkọ san, ko to di pe ẹ san owo yooku laaarin oṣu mẹfa si ọdun kan gbako.
 
Pelican Ecostay Apartments: Ile adagbe oni yara mẹta, 3 Bedroom Fully-Detached Bungalow wa fun tita, eyi ti wọn ti pari jẹ miliọnu mọkandinlọgbọn aabọ (₦29.5m); eyi ti ko tii pari jẹ miliọnu mẹtadinlogoji le diẹ (₦37.250m).
 

Pelican Brief: Miliọnu mẹta aabọ naira (₦3.5m) ni ilẹ Pelican Brief jẹ. Miliọnu kan naira lẹ maa kọkọ san, ẹ si maa san eyi to ku laaarin oṣu mẹfa gbako lai ni ele ninu.
 
Ọna irọrun ni ẹ le gba di onile ati onilẹ niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun pẹlu ileeṣẹ Pelican.
 
Gbogbo awọn ilẹ ati ile wọn lo ni ontẹ ijọba ninu.


Fun alaye lẹkunrẹrẹ, ẹ le kan si awọn alaṣẹ lori 08024506873, 08061276787. Ẹ si tun le mọ si nipa wọn lori ikanni wọn www.pelicanestate.ng


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI