Ẹ wo oju Chioma, ọmọbinrin to n digunjale n'ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 29, 2022

Ẹ wo oju Chioma, ọmọbinrin to n digunjale n'ipinlẹ Ogun


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ọdọmọbinrin, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, Chioma Okafor, ẹni ti wọn sọ pe ko n'iṣẹ meji to kọja iṣẹ adigunjale lọ lagbegbe Mowe, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ naa.
 
A gbọ pe ibi ti Chioma ati ẹnikeji rẹ, Nweke Joshua, toun jẹ ọmọ ọdun mọkandinlogun ti n digunjale lọwọ ni ọwọ palaba wọn ti segi, iyẹn l'ọjọ Ẹti, Furiadee, ọsẹ to kọja yii.
 
Nnkan bi aago mẹsan aabọ alẹ ọjọ naa ni iroyin fi to wa leti pe ọwọ tẹ awọn mejeeji lakoko ti wọn digun lọ si ṣọọbu kan ti wọn ti n ta eroja ounjẹ ni ikorita Safari to wa lagbegbe Adesan.
 
Bi wọn ṣe debẹ la gbọ pe wọn ti yọ ibọn si ẹni to ni ṣọọbu ọhun, ti wọn si gba gbogbo owo to pa lọjọ naa.
Ibi ti wọn ti n ṣọṣẹ lọwọ ni wọn lawọn to kofiri wọn ti ranṣẹ s'awọn ọlọpaa ati oṣiṣẹ aabo So-Safe Corp, ti a si gbọ pe wọn ko fi falẹ rara ti wọn fi lọ koju wọn.

Nigba tọwọ palaba wọn segi, l'awọn ọlọpaa ati So-Safe, to fi mọ awọn ara agbegbe naa too mọ pe ayederu ibọn ni wọn fi n digunja;e kaakiri.
 
Ọmọdekunrin naa ninu ọrọ rẹ sọ pe Chioma lo mu aba wa wi pe k'awọn lọ jale, lati le ri owo maa fi jẹun, to si ni ọmọbinrin naa lo lọ ra ayẹderu ibọn ti wọn lo.
 
Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa sọ pe ọga awọn Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lẹkunrẹrẹ, ko to di pe wọn foju wọn ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI