Ẹ wa a gbọ o! Ilu Abẹokuta fẹẹ gbalejọ ọpọ awọn amuludun l'oṣu kejila - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 29, 2022

Ẹ wa a gbọ o! Ilu Abẹokuta fẹẹ gbalejọ ọpọ awọn amuludun l'oṣu kejila


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari patapata bayii fun ilu Abẹokuta ipinlẹ Ogun lati gbalejo awọn gbajugbaja ati ogbontarigi lagbo amuludun kaakiri ipinlẹ Ogun ati agbegbe rẹ.
 
A gbọ pe ẹsẹ ko nii gbero niluu Abẹokuta lọjọ naa, iyẹn ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun ti a wa yii, nibi akanṣe eto ti wọn pe ni 'Unity Concert', eyi ti ileeṣẹ Tunsfat Communications Int'l to jẹ ti ilu-mọ-ọn-ka pedepede, Babatunde AbdulGafar Okunade ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ọmọọba ṣagbatẹru ẹ.
 
Gbagede iṣere Panṣẹkẹ, iyẹn Skating Ground to wa lagbegbe Post Office niluu Abẹokuta ni eto ọhun yoo ti waye, nibi ti awọn adẹrinpoṣonu, oṣere tiata, olorin ẹmi ati musulumi, olori Fuji ati bẹẹbẹẹlọ yoo ti fi dawọn eeyan laraya.
 
Bo tilẹ jẹ pe ipalẹmọ eto naa ti n lọ lori redio Smash 88.1FM to wa niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti n yanna-naa awọn olorin, adẹrinpoṣonu, at'awọn amuludun loriṣiriṣi to n bọ lọjọ naa. Aarin aago mẹrin si aago mẹrin aabọ irọlẹ, gbogbo Ọjọbọ, Tọsidee  ni eto ti wọn pe ni Unity Concert n waye lori redio naa.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni gbogbo awọn to ba wa lọjọ naa ni yoo jẹ oriṣiriṣi ẹbun bii Kẹkẹ Maruwa, Ọkada, Ilẹ ati awọn ẹbun miran to jọju.
 
Bakan naa la tun gbọ pe ileeṣẹ Tunsfat Communications tun fẹẹ fi aami ẹyẹ da awọn eeyan lọla, paapaa awọn ti wọn ko lero wi pe wọn yoo gba aami ẹyẹ nigbesi aye wọn. 
 
Aago mẹwaa owurọ ni eto ọhun yoo bẹrẹ ni pẹrẹu. Ọfẹ la gbọ pe awọn eeyan yoo wọle lati gbadun ara wọn lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI