Ero rẹpẹtẹ lẹyin Gomina AbdulRazaq nibi iwọde t'ẹgbẹ oṣelu APC laaarin gbungbun Kwara gbe kalẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, November 26, 2022

Ero rẹpẹtẹ lẹyin Gomina AbdulRazaq nibi iwọde t'ẹgbẹ oṣelu APC laaarin gbungbun Kwara gbe kalẹ


Gbogbo ilu Ilọrin to wa n'ipinlẹ Kwara ni wọn fi idunnu wọn han si gomina AbdulRahman AbdulRazaq, ti wọn si l'awọn ṣetan lati ṣatilẹyin fun, ko le ṣejọba lẹẹkeji.
 
Ọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee, ana ni gbogbo awọn ọdọ ati obinrin, koda to fi mọ gbogbo awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa ni wọn jade lọpọ yanturu lati ṣe iwọde ipolongo saa keji fun gomina AbdulRazaq.

Wọn ni gbogbo awọn aṣeyọri AbdulRazaq loriṣiriṣi ẹka eto iṣejọba lo n tẹ wọn lọrun, paapaa bo tun ṣe mu ipinlẹ naa gbajumọ laaarin ọdun mẹta ataabọ to ti wa n'ipo naa.

Wọn ni iṣakoso rẹ ko ni ojusaaju ninu, bẹẹ ni ko fi ọrọ oṣelu ṣe ijọba rẹ, gbogbo awọn agbegbe ati igberiko to wa nipinlẹ naa lo ṣiṣẹ idagbasoke si, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.
 
Iwọde ti ẹgbẹẹgbẹrun araalu kopa ninu la gbọ pe alaga igbimọ ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, Ambasidọ Abdulfatai Yahya Seriki lewaju wọn ni wọn ti fi ọpẹ wọn han.
 
Ohun ti a gbọ ni pe woro si woro ni iwọde ipolongo naa de niluu Ilọrin ati agbegbe ẹ, nibi ti awọn olukopa ti ko oriṣiriṣi patako ti wọn kọ erongba idunnu wọon si, lati fi mọ riri ipa ti gomina naa n ko.
 
Iwọde ọhun la gbọ pe o waye lẹyin ti ẹgbẹrun mẹwa ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, SDP ati NNPP, to fi mọ awọn ẹgbẹ oṣelu miran lọ darapọ mọ APC lati ṣatilẹyin fun wọn.
 
Papa iṣere ipinlẹ naa to wa niluu Ilọrin la gbọ pe wọn ti gbera, ti wọn si yika gbogbo ilu, lati bii Surulere, Baboko, Ọja Ọba, Ọja Gambari, Ipata, Maraba, to fi mọ awọn agbegbe bii Post Office, Challenge titi de ileeṣẹ ẹgbẹ naa to wa loju ọna ilegbe awọn kọmiṣanna ni GRA.
 
Nigba to n sọrọ, alaga ẹgbẹ naa, Ọmọọba Sunday Fagbemi sọ pe ipa ti ẹgbẹ naa ti ko ninu idagbasoke ipinlẹ naa ko ṣee fọwọ rọ sẹyin laaarin ọdun mẹta ataabọ.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI