Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Falẹyẹ Sunday Ọlalẹyẹ ti sọrọ, o tun fi ọwọ sọya wi pe ipinlẹ naa ko nii gba omi, ko tun gba ẹyin laaarin oun pẹlu awọn ọdaran to fi ipinlẹ naa ṣe ibugbe.
Ana, Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee ni ọga Ọlalẹyẹ sọrọ naa niluu Oṣogbo lakoko to n fi oju ọdaran mọkandinlọgbọn han f'awọn akọroyin, nibi to ti sọ pe awọn ọdaran ko nii f'ọkan balẹ niluu naa mọ.
Lara awọn tọwọ tẹ la gbọ pe ẹsun ile, ija igboro, gbigbe ayederu iroyin, idigunjale, apaayan, jiji mọto gbe, lilu jibiti at'awọn miran ni wọn fi kan wọn.
A gbọ pe aake mẹta, ada mẹta, ibọn ilewọ kan, ọfa ati ibọn agbelẹrọ kan, to fi mọ oogun abẹnugọngọn loriṣiriṣi ni wọn gba lọwọ wọn.
Lara awọn nnkan miran ti wọn tun gba lọwọ wọn ni mọto Toyota Sienna ti nọmba idanimọ rẹ jẹ RBC999BQ; audio CD, mọto Ford Ranger to ni nọmba idanimọ KJA914YA, ibọn agbelẹrọ kekere kan, ọta ibọn, ọkada Bajaj kan foonuPartner kan, foonu Techno kan, mọto ayọkẹlẹ Toyota Corolla ti nọmba rẹ jẹ GGC990CY.
Awọn tọwọ tẹ naa ni: Babatunde Ibraheem, ọmọ ọdun mẹtalelogun; Babalọla Adebayọ, ọmọ ọdun mẹrinlelogun; Nnachi James, ọmọ ọdun mẹrinlelogun, ti ọwọ tẹ lori ẹsun ole jija; Otitọju Ọmọniyi, ọmọ ọdun mọkanlelogoji ati Adewale Oni, ẹni ọdun mẹtalelogoji la gbọ pe wọn gbe ayederu iroyin sita; ati Adigun Popoọla, ẹni ọdun marundinlogoji ti wọn mu f'ẹsun ole jija.
Salami Fatai, ọmọ ọdun marundinlọgbọn; Ogundipẹ Caroline, ọmọ ọdun mejilelogun ni wọn mu f'ẹsun idigunjale; Adepọju Sọdiq, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn; Wasiu Ọlalekan, ọmọ ọdun mẹrinlelogun; ati Rasheed Kamal, ẹni ọdun mejidinlọgbọn lọwọ tẹ fun ẹsun idigunjale.
Bakan naa ni ọwọ tun tẹ Fẹsọmade Abiọdun, ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn; Jafar Ubali Ibrahim, ẹni ọgbọn ọdun; Adekunle Orisunmibọla, ẹni ọgbọn ọdun; Azeez Famoriyọ, toun jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji fun ẹsun idigunjale, ipaniyan, jiji ọkọ gbe, jibiti, ole jija ati gbigba owo lọna ẹburu.
Awọn tọwọ ọlọpaa tun tẹ ni Oguniran Fẹranmi, ọmọd ọdun mẹẹdogun; Ọlayinka Damilọla, ọmọ ọdun mẹrindinlogun; Ọlabọsipo Afeez, ọmọ ọdun mẹrindinlogun; Ayọdeji Samson, ọmọ ọdun mẹtadinlogun; Adegoke Taofeek, ọmọ ọdun mẹẹdogun; Babatunde Ayọmide, ọmọ ọdun mẹrindinlogun ati Bọlatito Sunday, ọmọ ọdun mẹtadinlogun.
Siwaju sii lọwọ tun tẹ Owolabi Hammẹd, ọmọ ọdun mejidinlogun; Falẹyẹ Ọlalekan, ọmọ ọdun mẹẹdogun; Adegboroye Joseph, ọmọ ọdun mejilelogun; Mutiu Hammẹd, ọmọ ọdun mọkandinlogun; Jide Dare, ọmọ ọdun mejilelogun; Bọlarinwa Lukman, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn; ati Ismaila Ọlalekan, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.
No comments:
Post a Comment