Gendekunrin mẹta fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla laṣepọ ninu ọgba ileewe l'Akurẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, November 29, 2022

Gendekunrin mẹta fipa ba ọmọ ọdun mẹrinla laṣepọ ninu ọgba ileewe l'Akurẹ


Ọwọ palaba gendekunrin mẹta kan ti wọn fẹsun kan wi pe wọn fipa ba ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrinla laṣepọ karakara ti segi, bẹẹ ni wọn ti n bẹbẹ pe iṣẹ eṣu ni, awọn ko tun ni ṣe bẹẹ mọ.
 
Ipele kẹrin ti a mọ si SS1 la gbọ pe ọmọ ti wọn fipa ba laṣepọ naa wa nile ẹkọ girama tiluu Akurẹ, iyẹn Akure High School, ijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, ipinlẹ Ondo, koda, a gbọ pe ileewe kan naa ni gbogbo wọn jọ n lọ.
 
Idris Matthew, ọmọ ọdun mẹtadinlogun; Ọlawale Tobi, ọmọ ọdun mejidinlogun ati Ajayi Micheal, toun naa jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun l'awọn mẹtẹẹta ti a gbọ pe wọn fipa ba ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrinla ọhun laṣepọ karakara.
 
AWIKONKO gbọ pe ọmọdebinrin naa ti a fi orukọ bo laṣeiri lo lọ sinu igbo to wa ninu ọgba ileewe lati yagbẹ, lai mọ pe awọn mẹtẹẹta yii n tẹle oun lẹyin.
 
Wọn ni bo ṣe yagbẹ tan, to fẹẹ dide lati maa lọ, ni awọn mẹtẹẹta sare kii mọlẹ, ti wọn si fipa ba a laṣepọ. A tiẹ gbọ pe awọn mẹtẹẹta yii ni wọn ja ibale ọmọ naa.
 
Lara awọn to fi iṣẹlẹ yii to wa leti sọ pe niṣe ni ẹjẹ kun gbogbo aṣọ ileewe ọmọ naa nigba to pada si kilaasi pẹlu ibanujẹ.
 
Wọn lo ti pẹ ti awọn ọmọkunrin naa ti n da ọmọbinrin yii laamu wi pe ko fẹ awọn, ṣugbọn ti ko gba fun wọn, eyi ni wọn lo mu ki wọn pinnu lati wa gbogbo ọna lati fipa ba a laṣepọ.
 
Nigba to n f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami jẹ ko di mimọ pe awọn mẹtẹẹta ti wa lahamọ wọn, nibi ti wọn ti n ṣe iwadii wọn lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI