Gomina AbdulRazaq kẹdun iku Ọjọgbọn Akanbi, Giwa fasiti Kwara to jade laye lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 21, 2022

Gomina AbdulRazaq kẹdun iku Ọjọgbọn Akanbi, Giwa fasiti Kwara to jade laye lojiji


Bi awọn eeyan kaakiri agbaye ṣe n kẹdun iku Ọjọgbọn Muhammed Mustapha Akanbi, Giwa fasiti ipinlẹ Kwara to jade laye l'ogunjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2022, bẹẹ naa ni gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ ọhun, paapaa awọn akẹkọọ ati igbimọ alaṣẹ fasiti naa n kọminu lori iku ọga wọn.
 
Lara awọn ti wọn tun banujẹ lori iku Ọjọgbọn Akanbi ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ naa, ẹni to sọ pe iku naa ba ni lọkan jẹ pupọ, nitori pe ojiji lo ba wọn, ti wọn ko si ronu rẹ tẹlẹ.

Gonina AbdulRazaq ṣapejuwe Ọjọgbọn Akanbi gẹgẹ bi amọna tuntun fun fasiti to jẹ alakoso rẹ, nitori pe nipa imọ rẹ ni fasiti naa fi n lewaju lakoko yii.

O ni oloogbe naa lo ṣi iwe itan tuntun fun idagbasoke ati ilọsiwaju nipa eto ẹkọ, bẹẹ lo gbadura pe Ọlọhun Allah jẹ ko ri Al-jannah wọ nipa isinmi to lọ.
 
Bakan naa lo ba mọlẹbi ati gbogbo igbimọ alaṣẹ KWASU kẹdun iku oloogbe naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI