Ẹgbẹ PDP ni Kwara tun kagbako nla, oludije sipo gomina tẹlẹ ti ba APC lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 21, 2022

Ẹgbẹ PDP ni Kwara tun kagbako nla, oludije sipo gomina tẹlẹ ti ba APC lọ


Iroyin ti ko dun mọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ninu rara lasiko yii lo tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii, ti wọn si ni adanu nla lo jẹ fun wọn.
 
Oludije s'ipo gomina ipinlẹ Kwara labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nigba kan ri, Amofin Saadudeen Abdullahi Alikinla ni iroyin fi to wa leti pe o ti ba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lọ.
 
Funra Amofin Alikinla la gbọ pe o kede bo ṣe fi ẹgbẹ naa silẹ funra rẹ, to si ni gbogbo awọn ọmọ ẹyin oun patapata kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to sọ iipinlẹ Kwara papọ ni yoo tẹle oun lọ.

Alikinla, ẹni to jẹ ọkan lara awọn ẹyinju Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba orileede yii tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki la gbọ pe ẹgbẹẹgbẹrun awọn alatilẹyin rẹ lo ko lọ sẹgbẹ APC, pẹlu ileri wi pe awọn ọmọ ẹyin ohun naa ṣi n bọ lati darapọ.
 
Nibi ipade wọọdu Jẹunkunu ti APC to wa nijọba ibilẹ Moro ni Alikinla ti kede sita wi pe oun ti wa darapọ mọ wọn, nitori pe iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tẹ oun lọrun.
 
O ni AbdulRazaq kii ṣe oloṣelu, bi ko ṣe adari tootọ ti kii ja awọn eeyan rẹ kulẹ, ati pe adari to n mu ileri ṣẹ lai wo ti ẹlẹyamẹya lo jẹ, to si tun jẹ anfaani nla fun ipinlẹ Kwara.

Alikinla, ẹni ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Akọbi Saraki sọ pe gbogbo atilẹyin to ba yẹ loun yoo ṣe fun AbdulRazaq lati pada sipo gomina lẹẹkeji, nitori pe gbogbo araalu patapata lo n sọrọ rẹ ni rere.
 
Alaga TIC nijọba ibilẹ Moro, Malaamu Isiaka Ganiyu Alikinla lo gba a wọle sẹgbẹ naa, to si jẹ ko ye awọn eeyan pe oriire nla lo jẹ fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI