Ileeṣẹ PELICAN VALLEY ESTATE tun fi itan tuntun balẹ pẹlu awọọdu 'AWOKỌṢE OODUA' ti wọn fi da wọn lọla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 27, 2022

Ileeṣẹ PELICAN VALLEY ESTATE tun fi itan tuntun balẹ pẹlu awọọdu 'AWOKỌṢE OODUA' ti wọn fi da wọn lọla


Lonii ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2022 ni ileeṣẹ Pelican Valley Estate, to n ta ile ati ilẹ, to fi mọ dukia tun fi itan tuntun balẹ pẹlu bi wọn ṣe gba aami ẹyẹ idalọla ara-ọtọ.

Kii ṣe pe ileeṣẹ Pelican Valley Estate labẹ ifọrukọsilẹ PELICAN VALLEY NIGERIA LIMITED deedee gba aami ẹyẹ idalọla naa, bi ko ṣe pe awọn ipa ti wọn n ko lawujọ lo fa a, ti wọn fi n mọ riri wọn.


Eto aami ẹyẹ naa ti ileese Flashlight Entertainment to n gbe magasiini Flashlight jade ṣagbatẹru ẹ, lo waye ninu gbọngan ayẹyẹ ti ile itura Continental Suites to wa ni Ibara niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Nigba to n sọrọ, alakoso ati oludasilẹ ileeṣẹ Flashlight Entertainment, Ọgbẹni Wọle Otuyẹlu sọ pe kii ṣe pe keeyan maa ṣe oore nikan, bi ko ṣe pe ki wọn maa ṣe oore fawọn ti ko le san an pada.


O ṣapejuwe alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Pelican Valley Estate, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ gẹgẹ bi awokọṣe pataki nilẹ Oodua, to si n fi ipa rere silẹ fawọn to n tẹle e.

Ọgbẹni Wọle Otuyẹlu ninu ọrọ rẹ sọ pe inu oun maa n dun nigbakugba toun ba n gbọ orukọ alakoso ileeṣẹ Pelican Valley Estate, nitori pe oun mọ oore nla to n ṣe fawọn eeyan, paapaa awọn to ku diẹ kaato fun.


Siwaju sii lo ni ọpọ awọn eeyan lo ti jẹ anfaani lara Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ nipa iṣẹ ti wọn n ṣe, pẹlu anfaani ara-ọtọ ti wọn n gbe kalẹ.

O ni awọn kan ti wọn ko ronu wi pe awọn maa ra ilẹ, depodepo wi pe wọn yoo di onile lori, ṣugbọn nipa anfaani owo sisan diẹ diẹ ti ileeṣẹ Pelican gbe kalẹ, ọpẹ ni wọn n da bayii.
 

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe awọn gbe eto naa kalẹ lati fi mọ riri ipa ti awọn eeyan n ko ninu idagbasoke ilu, eyi to nii ṣe pẹlu igbe aye irọrun fawọn eeyan.

O ni awokọṣe Oodua nii ṣe pẹlu awọn to ṣe iranlọwọ to yẹ fun awọn ti wọn mọ pe wọn ko le san oore naa pada la n pe ni awokọṣe Oodua, paa bii imura, irolagbara, ṣiṣe iranwọ nipa ohun to n jẹ awọn araalu logun.

Bẹẹ lo ni eeyan to maa n fẹ koun da yatọ ninu gbogbo ohun to ba n ṣe ni Ọmọwe Adeyẹmọ jẹ, to si loo dara lati maa mọ riri ipa ti a ba n ko lawujọ nigba ti a ba ṣi wa laye.


Ninu ọrọ tiẹ, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ sọ pe iwuri nla ni aami ẹyẹ naa jẹ foun, nitori pe kii nnkan toun n ro tẹlẹ, o ni ojiji lo ba oun nigba ti awọn to gbe eto naa kalẹ pe oun lati fi to oun leti.

O loun ko kuku mọ pe awọn eeyan wo nnkan toun n ṣe, eyi to sọ pe bi Ọlọrun ṣe ran oun loun ṣe n ṣe e.


Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe aami ẹyẹ kọkanlelogun ree toun yoo gba laaarin oṣu meji.

O rọ awọn ọdọ lati jawọ ninu iwa jibiti paapaa jibiti ori ikanni ayelujara ti a mọ si Yahoo-Yahoo, to si ni ọpọ anfaani lo wa nilẹ ti awọn ọdọ le fa mọra lati fi di ọlọrọ ati ọlọla ni Naijiria.

O ni latigba toun ti bẹrẹ iṣẹ tita ilẹ lọdun meje sẹyin, oun ko tii lu jibiti ri, ati pe lati bi ọdun mẹwaa ti wọn ti wa lẹnu ẹ, ko tii sẹni to fẹsun jibiti kan wọn ri, tabi pe ki wọn gbe wọn lọ sile ẹjọ.

Bẹẹ lo dupẹ lọwọ awọn to gbe eto naa kalẹ fun bi wọn ṣe ronu kan wọn fun aami ẹyẹ idalọla ara-ọtọ naa.

Diẹ ree lara fọto bi eto naa ṣe lọ si:















No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI