Wọn ti bura f'Adeleke l'Ọṣun gẹgẹ bii gomina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, November 27, 2022

Wọn ti bura f'Adeleke l'Ọṣun gẹgẹ bii gomina


Lonii, ọjọ Aiku, Sannde ni wọn bura fun gomina tuntun ti wọn dibo yan nipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke.

Nnkan bi aago mejila ku iṣẹju mẹẹdogun ni Onidajọ agba Oyebọla Adepele-Ojo bura fun Adeleke niwaju gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa niluu Oṣogbo.

AWIKONKO gbọ pe aago mọkanla kọja ogun iṣẹju ni Adeleke ati ikọ akọwọrin rẹ de si gbagede ibura, to si gun ori pepele ti wọn ti bura fun un.

Lara awọn to wa nibẹ ni aburo rẹ to jẹ gbajugbaja olorin takasufee nni, David Adeleke ti ọpọ awọn eeyan mọ si Davido.

Ni bayii, Sẹnetọ Adeleke ni gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI