Ipo Ọba Orile-Ilawọ: Awọn araalu parọwa si Ogunsanya lati gba kamu, ko si ye e fapajanu kaakiri mọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, November 2, 2022

Ipo Ọba Orile-Ilawọ: Awọn araalu parọwa si Ogunsanya lati gba kamu, ko si ye e fapajanu kaakiri mọ


Pupọ ninu awọn ara ati olugbe ipinlẹ Ogun ni wọn ti parọwa si ọkan lara awọn oludije s'ipo ọba ilu Orile-Ilawọ to wa n'ijọba ibilẹ Ọdẹda ipinlẹ Ogun, Lawrence Ogunsanya lati gba kamu, ko si lọ f'ọkan ara rẹ balẹ, ati pe ko fọwọsowọpọ pẹlu ẹni ti ijọba fa kalẹ, ki idagbasoke le de ba ilu naa.

Ori redio Splash FM to wa ni Abiọla Way niluu Abẹokuta, ipinlẹ naa l'awọn araalu ti gba ọkunrin naa lamọran lati fi ẹdọ lori orooro lori ipo to n du naa, iyẹn lori eto ti wọn pe ni 'Oju Abẹ', nibi ti Ogunsanya ti lọ fi ẹdun ọkan rẹ han.

Ṣaaju asiko naa, Ogunsanya fẹsun kan ijọba ibilẹ Ọdẹda wi pe awọn ni wọn ṣe magomago lori bi wọn ṣe kede Oluṣẹgun Alexander MacGregor gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo to waye niluu Ẹlẹgunmẹfa to jẹ orile ilu Ilawọ.

Alaga ijọba ibilẹ Ọdẹda, Ọnarebu Arabinrin Fọlaṣade Adeyẹmọ, nigba toun naa n tako ẹsun ti Ogunsanya fi kan an, o ṣalaye pe gbogbo igbesẹ t'awọn gbe lori eto idibo to gbe MacGregor wọle gẹgẹ bi ọba, lo lọ nibamu pẹlu ofin oye jijẹ, ati pe awọn gba aṣẹ ati itọni lọwọ ileeṣẹ to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ naa ni.
 
O jẹ ko di mimọ pe bi Oluwo ilu Ilawọ ko ṣe si nibi eto idibo naa ko ni nnkan ṣe pẹlu ilana ti wọn fi yan ọba, nitori pe gbogbo oloye ti wọn yan lati rọpo awọn afọbajẹ, iyẹn Warrant Chiefs, ko si olori kankan laaarin wọn.

Bakan naa, Oluwo ilu Orile-Ilawọ, Oloye Oluwọle Dosunmu ninu ọrọ rẹ sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ko si nibi ti wọn ti ṣeto idibo naa, nitori pe oun ko mọ pe asiko ti to, o ni oun ti kamu lori ẹni ti wọn fa kalẹ fun ipo ọba.
 
Oloye Dosunmu ninu ọrọ rẹ sọ pe "Mi o ni ẹni ti mo n ṣatilẹyin fun ninu awọn marun-un to gba fọọmu lati du ipo ọba ṣugbọn. To ba jẹ pe MacGregor naa ni wọn fa kalẹ, mo fara mọ ọn."
 
Pupọ awọn araalu to pe sori eto naa ni wọn sọ pe ki Ogunsanya lọ ṣe suuru, nitori pe bi aigbọra ẹni ye lohun to n fa wahala to wa nilẹ naa, ati pe to ba le ṣe suuru daadaa, awọn oloye yoo jokoo lati ṣeto bi wọn yoo ṣe maa yan ọba ninu idile kọọkan ninu eto ọba jijẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI