Kọkọrọ to ṣilẹkun alaafia lawọn ọba alaye jẹ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 21, 2022

Kọkọrọ to ṣilẹkun alaafia lawọn ọba alaye jẹ ni Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣapejuwe awọn ọba alaye gẹgẹ bi kọkọrọ to n ṣilẹkun alaafia fun idagbasoke ilu, to si ni wọn ko ṣee pati lailai.

AbdulRazaq lo sọrọ naa lopin ọsẹ to ṣẹṣẹ kọja yii, to si ni ohun elo gidi ni wọn jẹ fun alaafia, ilọsiwaju ati idagbasoke nipinlẹ naa, ati pe iṣakoso ohun gbe wọn si ipo nla pẹlu ọwọ gidi nipa ipa rere ti wọn n ko.

Nibi ayẹyẹ igbade ogun ọdun ati ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun ti Ọba Onipẹ tiluu Ipẹẹ, Ọba Muftau Adebayọ Lawal, Titiloye kẹta to wa nijọba ibilẹ Oyun ni Gomina AbdulRazaq ti jẹ ko di mimọ pe oun ko le ṣai bọwọ f'awọn ọba alaye fun iranlọwọ ti wọn n ṣe lori idagbasoke ilu.

Nibẹ lo ti gbe oṣuba kare fun Ọba Onipẹ fun bi alaafia ati ilọsiwaju ṣe n jọba niluu Ipẹẹ, to si ni apẹẹrẹ rere ni kabiyesi naa jé fun gbogbo ọmọ ilu.
 
Lara awọn to kọwọrin pẹlu gomina ni igbakeji rẹ, Kayọde Alabi; alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, Oloye Sunday Fagbemi; ati Alaaji Abdulrazaq Jiddah.

Awọn miran to tun wa nibẹ lawọn ọba alaye bii Ọlọfa tiluu Ọffa, Ọba Mufutau Gbadamọsi Eṣuwoye II; Olupo tiluu Ajaṣẹ-Ipo, Ọba Ismaila Yahaya Alebioṣu; Elese tiluu Igbaja, Ọba (Ọmọwe) Ahmẹd Awuni Babalọla, Arepo III; Olomu tiluu Omu-Aran, Ọba Abdulraheem Ọladele Adeoti; Elerin tiluu Erin-Ile, Ọba Abdulganiyu Ajibọla Olusokun II; Olupako tiluu Ṣharẹ, Ọba Haruna Ọlawale Suleiman.
 
Bakan naa ni alakoso agba fun ileewe Michael Imoudu National Institute for Labour Studies, Kọmureedi Issa Arẹmu; alaga eto naa naa, Amofin Abdulateef Fagbemi; Aarẹ ẹgbẹ ọmọ ilu Ipẹẹ, Ipee Progressive Union (IPU), Onimọ-ẹrọ Mọshood Abiọdun Anifowoṣe; alaga igbimọ igbaninimọran tiluu Ipẹẹ, Ipee Advisory Council, Oloye Ọlabọde Afọlayan; atawọn miran ni ko gbẹyin nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI